Ijọba ipinlẹ Ọyọ tí kede pe ọwọ ti tẹ ọkunrin kan to n ta ayederu fọọmu igbanisiṣẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ Amọtẹkun, ẹka ipinlẹ naa.
Adeyẹmi Agboọla ni wọn pe orukọ ọkunrin yii, agbegbe kan to n jẹ Durbar, ni Stadium Road, niluu Ọyọ, ni ọọfiisi rẹ wa, nibi tawọn eeyan ti maa n lo ẹrọ ayara bii aṣa, nibẹ naa lo ti n tẹ ẹ jade, to si n ta a fun araalu.
Wẹsidee, Ọjọruu, ọsẹ yii, lọwọ tẹ ẹ pẹlu fọọmu mọkanla lọwọ to jẹ ayederu. Wọn ni ẹẹdẹgbẹta Naira lo n ta a fawọn araalu. Ni bayii, o ti wa lọdọ ijọba, nibi to ti n ṣalaye ohun to mọ nipa ẹsun ọhun.