Ẹ wo awọn ọmọọlewe girama tọwọ tẹ nibi ti wọn ti n fa igbo ni Ṣaki

Olu-theo Omolohun, Oke-Ogun

Ọwọ awọn ẹṣọ alaabo to n tọpinpin iwa ibajẹ laarin awọn ileewe girama lorileede yii, ẹka tilu Ṣaki, iyẹn CNC Legion ti tẹ awọn afurasi ọdaran marun-un kan nibi ti wọn ti n mu igbo atawọn egboogi oloro mi-in ninu igbo Veterinary, niluu naa, wọn lakẹkọọ ileewe girama ni wọn, akẹkọọ-binrin meji wa ninu wọn.

Orukọ awọn afurasi ti wọn ni wọn jẹ ọmọleewe Girama Muslim Secondary Grammar School, to wa laduugbo Darusalam, lọna to lọ si ilu Igboorọ ni: Ọlanrewaju Kẹhinde, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, to ni iṣẹ gẹrun-gẹrun (barber) loun kọ lẹyin toun jade nileewe naa lọdun to koja, Asamu Mọnsuru, ọmọ ọdun mejidinlogun, to n gbe laduugbo Kini-kini, ati Jimọh Saheed toun wa ni kilaasi SS2.

Awọn obinrin ti wọn fẹsun kan pe wọn jọ n fagbo nibi tọwọ ti tẹ wọn ni Hazan Zainab, ọmọ ọdun mọkandinlogun ati Wosilat Saheed, ipele ẹkọ keji tawọn to ṣẹṣẹ wọ girama (JSS 2) ni wọn lawọn mejeeji wa.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Ọga awọn agbofinro naa, Pasitọ Mathew Okoro, ni ni deede aago meji aabọ ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, loun gba ipe lati ileewe naa pe awọn afurasi ọmọọleewe naa n daamu awọn araadugbo, wọn niwa jagidijagan ni wọn n hu ti wọn ba ti gba kinni wọn yo, wọn si fẹ kawọn ẹṣọ alaabo naa gba awọn.

O tẹsiwaju pe lati ilu Ibadan toun ti n ṣe ipade kan lọwọ lori eto aabo loun ti paṣẹ fawọn oṣiṣẹ to wa larọọwọto ni Ṣaki lati tete gbe igbesẹ lori igbe tawọn araalu ke naa, ọwọ si ba awọn maraarun yii bo tilẹ jẹ pe awọn mi-in raaye sa lọ.

Yatọ si ti igbo mimu, awọn nnkan mi-in ti wọn tun ba lara awọn afurasi ọdaran yii ni egboogi tramadol tijọba ti fofin de, iṣana, ọbẹ oloju meji, ati oogun abẹnu gọngọ.

Pasitọ Okoro sọ pe gbara ti wọn ko wọn de ọfiisi wọn to wa laduugbo Balakọ, niluu Ṣaki, ni wọn ti ranṣẹ pe awọn obi awọn akẹkọọ ọhun lati fi ọrọ naa to wọn leti, ki wọn le mọ iwa buruku tawọn ọmọ wọn n hu.

Okoro ni awọn yoo taari gbogbo wọn sọdọ ọlọpaa lati tubọ ṣewadii, ki wọn si gbe igbesẹ to kan lori wọn, lọna ofin.

Leave a Reply