Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti taari baba agbalagba ẹni ọdun mejilelaaadọrin(72) torukọ ẹ n jẹ Ishọla Tijani, si ẹka to n ri si ifiyajẹ awọn ọmọde. Ọmọ ọdun meje ni baba yii fipa ba lo pọ lọjọ kejilelogun oṣu kẹsan-an yii, n’Ipẹru.
Alaye ti iya ọmọ naa ṣe fawọn ọlọpaa ni pe oun jade lọ lọjọ naa ni, oun si fi ọmọ oun obinrin, ọmọ ọdun meje silẹ ninu ile.
O ni nigba toun pada de loun ba ọmọ naa ninu inira gidi, nigba toun si beere ohun to n ṣe e lọwọ rẹ, ọmọbinrin naa sọ pe Alagba Ishọla Tijani lo mu oun wọn yara rẹ to si ki kinni ẹ bọ toun, to ba oun ṣere to mu inira wa naa.
Kia ni iya ọmọ yii gba teṣan ọlọpaa Ipẹru lọ lati fẹjọ sun, ẹsẹkẹsẹ naa si ni DPO ibẹ ti ko awọn ikọ rẹ lẹyin lọ sile ti iṣẹlẹ yii ti waye, wọn si mu baba agba to ba ẹgbẹ ọmọ-ọmọ ẹ lo pọ naa.
DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ yii to AKEDE AGBAYE leti, ṣalaye pe baba naa ti jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ ọdun meje yii sun. O ni gedegbe ni ayẹwo si fi han lọsibitu pe ibale ti sọnu lara ọmọdebinrin yii .
Nitori iṣẹlẹ yii, Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, rọ awọn obi lati maa mọ ẹni ti wọn yoo fi ọmọ wọn ṣọ bi wọn ba n jade.
O ni awọn ikooko to wọṣọ aguntan lo pọ laarin awujọ wa, ti wọn n wa ọmọ kekere ti wọn yoo ba laye jẹ.