Ẹ wo bi wọn ṣe mura bii ṣọja, agbebọn to n ṣiṣẹ ajinigbe ni wọn ni Kaduna

Faith Adebọla

Iṣẹ ṣọja tootọ leeyan maa kọkọ ro pe awọn mẹtẹẹta tọwọ awọn agbofinro ba yii n ṣe pẹlu bi wọn ṣe ko aṣọ kaki ṣọja sọrun, ti wọn tun de fila ologun si i, ṣugbọn elewu eniyan ni wọn, lara afurasi afẹmiṣofo ti wọn n fooro ẹmi awọn araalu ni Kaduna ni wọn.

Orukọ tawọn agbebọn naa lawọn n jẹ ni Adamu Bello, Isiaku Lawal ati Muazu Abubakar. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa apapọ, Ọgbẹni Frank Mba, lo ṣafihan wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, niluu Abuja, wọn lawọn ikọ to n gbogun ti iwa idigunjale lo mu wọn laipẹ yii, wọn si patẹ awọn ibọn ti wọn fi n ṣiṣẹẹbi naa siwaju wọn.

Nigba tawọn oniroyin n beere ọrọ lọwọ wọn, awọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe awọn wa lara awọn agbebọn to ṣakọlu sileewe Bethel Baptist School, niluu Kaduna, nibi ti wọn ti ji awọn ọmọleewe bii ogoje (140) gbe lọjọ karun-un, oṣu keje, ọdun yii, wọn lawọn mẹẹẹdọgbọn lawọn ṣiṣẹ ọdaju naa.

Abubakar, to pe ara ẹ lẹni ọdun mẹtadinlọgbọn sọ pe “awa mẹẹẹdọgbọn la lọọ ṣiṣẹ naa lọjọ yẹn, ọmọleewe mẹrindinlogoje la ji ko, bo tilẹ jẹ pe awọn kan lara wọn sa lọ mọ wa lọwọ lọna. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira lowo ti wọn pin femi ninu owo itusilẹ tawọn ọga wa gba.”

Adamu ni tiẹ sọ pe loootọ lawọn yinbọn pa awọn ẹṣọ ọlọdẹ ti wọn n sọ ọgba ileewe ọhun, o nigba ti wọn ko fẹẹ tete mu awọn lọ sibi tawọn ọmọleewe naa n sun si lawọn dana ibọn ya wọn.

Bi Frank Mba ṣe wi, iwadii ṣi n tẹsiwaju lori wọn, o lawọn agbofinro ṣi n ba iṣẹ lọ lati ri awọn agbebọn to ku mu, ki wọn le jere iṣẹ ọwọ wọn.

Leave a Reply