Ẹ wo Kabiru, ayederu ṣọja to n halẹ m’awọn araalu

Faith Adebọla, Eko

 

 

Beeyan ba ri ọkada ti Kabiru Mohammed yii n gun lọọọkan, eeyan aa kọkọ ro pe ṣọja ni, tori ọda ileeṣẹ ologun lo fi kun un, ṣọja ni wọn loun naa si maa n pera ẹ, kawọn agbofinro too foju ẹ bale-ẹjọ.

CSP Shọla Jẹjẹloye, alaga ikọ amuṣẹṣẹ to n mu awọn onimọto ati ọlọkada to ba lufin irinna l’Ekoo lo sọrọ yii di mimọ, o lọjọ Abamẹta, Satide, lọwọ ba afurasi ọdaran naa, nibi to ti n gbe ọkada rẹ kọja loju ọna marosẹ Eko si Abẹokuta, tijọba ti fofin de fawọn ọlọkada.

Nibi tọkunrin naa ti n lu ọlọkada kan nilukulu lo lawọn ti de ba wọn, ṣugbọn ọkunrin naa ni ṣọja loun, nigba tawọn si beere kaadi idanimọ ẹ, wọn lo fesi pe ṣoju wọn fọ, ṣe wọn o riran ri i pe alupupu akanṣe ti ọda ileeṣẹ ologun wa lara ẹ loun n gun ni.

Ibi tọrọ de ree ti wọn fi lawọn o ni i jẹ kọkunrin naa tabi alupupu rẹ lọ lai jẹ pe wọn ri aridaju boya ṣọja tootọ ni tabi irọ ni. N lakara ba tu s’epo pe awuruju ṣọja lọkunrin naa, ko tiẹ gba ọna ileeṣẹ ologun kọja ri.

Oju-ẹsẹ lo lawọn ti fi pampẹ ofin gbe e, ti wọn si wọ ọ lọ siwaju adajọ ni kootu alagbeekan kan to wa nitosi. Ẹsun mẹta ni wọn ka si i lẹsẹ, wọn lo bawọn eeyan ja, o n huwa to le di alaafia ilu lọwọ, o si tun n pe ara ni ohun ti ko jẹ.

Kabiru fẹnu ara ẹ rojọ, o loun gba pe oun jẹbi, o jẹwọ pe niṣe loun mọ-ọn-mọ kun ọkada oun si ọda tawọn ṣọja n lo, koun le maa fi ṣe arumọjẹ fawọn agbofinro, tori ki wọn ma baa da oun duro toun ba gbe ero, tabi toun rin lawọn ọna tijọba ti fofin de ọlọkada lati rin l’Ekoo.

Ṣa, lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ, Adajọ Oyebimbọla Isreal Adelakun ni oun ṣaanu ọkunrin naa, ṣugbọn ko sare lọọ fi ẹwọn oṣu mẹfa pere jura, ko le jẹ arikọgbọn fawọn mi-in. Wọn si fun un lanfaani lati sanwo itanran ẹgbẹrun lọna ogoji naira, wọn tun paṣẹ pe ko gbagbe nipa ọkada ẹ, ijọba ti gbẹsẹ le e.

Leave a Reply