Faith Adebọla, Eko
Kayọde Adeyanju lorukọ baba ẹni ọdun marundinlaaadọta yii, ṣugbọn o ti dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii latari bi ọmọ bibi inu ẹ, ọmọ ọdun mẹrinla, ṣe lọọ fẹjọ ẹ sun ni teṣan ọlọpaa Ipakodo, lagbegbe Ikorodu, pe ki wọn waa gba oun lọwọ baba oun, o ti fẹẹ fi ibasun ba oun laye jẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe laarin ọsẹ to kọja yii lọmọ naa wa si teṣan ọlọpaa funra ẹ, ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ keje, oṣu kẹfa, yii, lo ba bẹrẹ si i ṣalaye ohun ti baba rẹ n fi oju rẹ ri.
Gẹgẹ bo ṣe wi, wọn lọmọbinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri naa ṣalaye pe ile kan naa loun ati baba oun n gbe, ile naa wa ni adugbo Ṣọọṣi Ridiimu, Tinubu Estate, Ibeshe, Ikorodu, nipinlẹ Eko.
Wọn lọmọ naa sọ pe o ti pẹ ti baba oun ti n ki oun mọlẹ, toun ko si le sọ fẹnikan, tori oun ko mọ bi nnkan naa ṣe n ṣẹlẹ, ati pe mama oun ko si lọdọ awọn. Wọn lo ṣalaye pe ọpọ igba loun maa n bẹ baba naa pe ko ma ṣe bẹẹ, ṣugbọn to jẹ tipatipa lo fi n ba oun sun, ko si ṣee ṣe foun lati gba ara oun lọwọ ẹ, tori o ti sọ pe oun maa pa oun ni toun ba sọ fẹnikẹni.
Kia lawọn ọlọpaa ti tẹle ọmọbinrin naa lọ sile ọhun, pẹlu irọrun si ni wọn fi pampẹ ofin gbe Kayọde.
Wọn ni baba yii ko ri ọrọ sọ nigba ti wọn bi i boya ọmọ rẹ purọ mọ ọn ni, niṣe lo n wolẹ, ko fesi kan.
Ọrọ yii ti de etiigbọ kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari baba naa sawọn ọtẹlẹmuyẹ to n bojuto iru ẹsun bii eyi ni Panti, Yaba, ibẹ ni wọn ti n ba iwadii lọ bayii. Wọn ni lẹyin iwadii, Kayọde maa lọọ wi tẹnu ẹ niwaju adajọ laipẹ.