Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ awọn ẹsọ alaabo ilu Ondo ti tẹ tẹgbọn-taburo kan, Sẹgun ati Azeez Adeoye, ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe n para wọn nipakupa niluu Ondo ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo lati bii oṣu diẹ sẹyin.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn ọmọ iya meji ọhun ati ẹnikan ti wọn n pe ni Isaiah ni wọn fẹsun kan pe wọn ṣeku pa fijilante kan, Ṣeun Akinsiku, si agbegbe Oke-Agunla, niluu Ondo, lọjọ kẹtalelogun, oṣu keje, ọdun ta a wa yii.
Ọjọ kẹrin lẹyin eyi, iyẹn lalẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn, osu kan naa, ni wọn lawọn mẹtẹẹta tun pa ẹlomi-in tawọn eeyan mọ si, Owolabi Ọladele.
Ọladele to jẹ akẹkọọ ọlọdun kẹta lẹka ti wọn ti n kọ nipa ẹṣin Kristiẹni nile-iwe olukọni agba Adeyẹmi la gbọ pe wọn pa si adugbo Tẹrẹrẹ, lagbegbe New Town, l’Ondo.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn lọwọ tẹ Isaiah ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi, oun lo si darukọ Sẹgun ati Azeez lasiko ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo.
Awọn ikọ ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ni wọn tun mori le gbọngan Civic Centre to wa lagbegbe Sabo lọjọ yii kan naa, nibi ti wọn ti ṣe ọkan ninu awọn ẹsọ Peace Corps to n ṣọ ibẹ leṣe yannayanna ki wọn too sa lọ.
Ṣe ni idunnu ṣubu layọ fawọn ọdọ ilu Ondo l’Ọjọruu, Wẹsidee ọsẹ yii, nigba tọwọ apapọ awọn ẹsọ alaabo, ninu eyi ta a ti ri, ẹsọ Amọtẹkun, awọn ọlọpaa, OPC atawọn ọmọ ẹgbẹ to n mojuto eto aabo ilu Ondo pada tẹ ọmọ iya kan naa ti wọn n huwa buruku yii.
Awọn mejeeji ni wọn ti n ṣeto ati fi ṣọwọ si olu ileesẹ ọlọpaa to n gbogun ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun l’Akurẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ lọwọ.