Ẹ wo Saliu, ọkada lo ji gbe ni teṣan ọlọpaa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ẹgbẹrun saamu ọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Saliu Yusuf yii ko ribi sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ o, ọwọ awọn agbofinro pada tẹ ẹ lẹyin oṣu marun-un to ti huwa ọdaran, ọkan lara awọn ọkada ti tawọn ọlọpaa paaki si teṣan wọn ni Dalekọ, Muṣhin, nipinlẹ Eko, ni wọn lọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn naa ki mọlẹ lasiko rogbodiyan ta ko SARS to waye lọdun to kọja, lo ba ji i gbe lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi ṣalaye f’AKEDE AGBAYE ninu atẹjade kan to fi lede pe nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ Ọjọruu, Wẹsidee yii, lọwọ ba afurasi ọdaran yii, awọn ọlọpaa to n patiroolu lagbegbe Mushin ni wọn mu un, pẹlu ọkada ti nọmba ẹ jẹ APP 476 Q to n gun kiri igboro.

Wọn ni bi wọn ṣe da Saliu duro ko kọkọ fẹẹ duro, niṣe ni wọn le e mu, wọn si beere iwe ọkada to gun, lọrọ ba di wo mi n wo ẹ, ko fesi kan ju pe ọkada oun ko niwee, igba ti wọn wo nọmba ara ọkada naa lawọn ọlọpaa ri i pe ọkada ti wọn ti n wa latigba rogbodiyan SARS tawọn janduku ṣakọlu si teṣan Dalekọ loṣu kẹwaa, ọdun to kọja ni. Wọn lọwọ awọn afurasi adigunjale kan ni wọn ti gbẹsẹ le ọkada naa, ti wọn si ṣi n ṣẹjọ lori ẹ lọwọ.

Nigba ti wọn tubọ wadii ọrọ wo lẹnu Yusuf yii, wọn lo jẹwọ pe oun loun ji ọkada naa gbe lasiko naa, wọn lo lẹyọ kan pere loun ji ninu awọn ọkada ọhun.

Atoun ati ọkada ọhun ti kọja sakata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, ibẹ ni wọn lawọn ikọ akanṣe kan to n wadii awọn ẹsun to jẹ mọ ti EndSARS ti n gba a lalejo lẹnu iṣẹ iwadii wọn.

Ti wọn ba ti pari iṣẹ iwadii wọn, Olumuyiwa ni Saliu maa balẹ si kootu ni, ibẹ lo ti maa ṣalaye ara ẹ labẹ ofin.

 

Leave a Reply