Aderounmu Kazeem
Teṣan awọn ọlọpaa ni Ẹlerẹ l’Agege ni Afaa Owolobi Yusuf ti n sọ nnkan to mọ nipa iku Toluwalaṣẹ ti wọn sọ pe o fi ọmọ odo lu pa n’Ikorodu.
Ninu alaye ti awọn mọlẹbi ọmọ ogun odun yii ṣe fawọn oniroyin, wọn ni lọjọ kejidinlọgbọn oṣu keje ni Toluwalaṣẹ Kembi, to ṣẹṣẹ pari ẹko Poli ẹ kuro nile, to dagbere wi pe oun fẹẹ lọ ba ẹnikan n’Ikorodu.
Ibi to dagbere yii naa ni wọn lo lọ o, ṣugbọn ti ko pada sile mọ. Ẹgbọn ẹ, Abimb̀ọla ninu ọrọ tiẹ sọ pe, lẹyin ti Tolu kuro nile ni ọrẹkunrin ẹ tawọn mọ daadaa, Ṣegun pe sori aago to si sọ pe ọmọbirinrin naa ti pe oun, o si ti sọ pe lọdọ ẹni ti oun lọ loun yoo sun.
Wọn ni nigba ti ilẹ mọ, ti awọn pe nọmba ẹ, niṣe ni ẹrọ ibanisọrọ ẹ ko dun mọ rara, nibẹ gan-an lawọn ti ko si wahala ọhun.
Lojuẹsẹ ni wọn ti fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti lẹgbẹẹ ile wọn ni Tabọn-tabọn l’Orile Agege. Ninu iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti tọpasẹ foonu ọhun de adugbo kan to n jẹ Ladega n’Ikorodu nibi ti wọn sọ pe Afaa Yusuf n gbe. Nibẹ naa ni aṣiri ti tu wi pe ̀ọkunrin naa lo pa a, ọmọ odo lo si fi lu u pa loruganjọ.
Wọn ni ni kete to ṣiṣẹ ibi ọhun tan ni Afaa yii ti salọ si ipinlẹ Kwara, ki ọwọ too tẹ ẹ ninu oṣu kẹjọ lẹyin ọsẹ kẹta to pa Tolu Kembe.
Afaa Yusuf ti jẹwọ o, alaye to ṣe ni pe ki i ṣe oun nikan loun ṣiṣẹ ibi naa, ati pe o ṣi ku awọn mẹta mi-in, ninu eyi ti babalawo kanti orukọ e n jẹ Owonikoko lawọn jọ ṣe e. Bakan naa lo fi kun un pe owo miliọnu meji naira ni wọn san lori ọmọ naa.
Agbẹnusọ Ileeṣe ọlọpaa naa ti sọrọ, Ọgbẹni Muyiwa Adejọbi, o ni loootọ niṣẹlẹ ọhun waye, bẹẹ lawọn ti n gbiyanju lati mu awọn yooku ti wọn jọ lọwọ ninu ẹ.