Faith Adebọla
Pampẹ ofin awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ti mu awọn adigunjale mẹta kan, Abayọmi Michael David, ti inagijẹ rẹ n jẹ Scofield, Oluwatosin Atilọla, ti wọn tun mọ si Tosine, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, nigba ti ẹni kẹta wọn, Sam Oluwatobi, jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun. Awọn mẹtẹẹta ti wa lakolo awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun bayii.
Gẹgẹ bi Oludari eto iroyin fun awọn ẹṣọ alaabo Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, ti wọn tun n pe ni So-Safe, Ọgbẹni Moruf Yusuf, ṣe sọ, o ni awọn olugbe agbegbe Iroko ati Arijẹ, niluu Ọta, nipinlẹ Ogun, ni wọn kegbajare si ọga agba So-Safe, Kọmandaati Sọji Ganzallo, lori foonu, wọn fẹsun kan an pe awọn kọlọransi ẹda kan ti di ẹrujẹjẹ saduugbo awọn, bi wọn ṣe n ja wọn lole foonu atawọn dukia wọn mi-in, bẹẹ ni wọn n fa ijangbọn, ti wọn ko si jẹ ki ọkan araalu balẹ rara.
Eyi lo mu ki Ganzallo paṣẹ fun ọmọọṣẹ ẹ, Ọgbẹni Tajudeen Ọdunmbaku, lati bẹrẹ patiroolu agbegbe naa lẹyẹ-o-sọka, wọn si fimu finlẹ daadaa, eyi lo jẹ ki wọn ri awọn afurasi ọdaran mẹta naa mu.
Ninu atẹjade ti Yusuf fi lede, o ni mẹrin ni ikọ adigunjale ọhun, amọ ẹni kẹrin wọn, Desmond Obani, tawọn eeyan mọ si Kokolet, ti wọn sọ pe oun lolori awọn ẹruuku ọhun ti sa lọ, wọn ṣi n wa a loju mejeeji bayii.
Yusuf ni iwadii ti fihan pe Ojule kẹtalelọgbọn, Opopona Unity Road, Abule Ijoko, ni Abayọmi n gbe, nigba ti Oluwatobi n gbe ni Ojule kẹrinlelogun, Ẹsiteeti Blessing, to wa l’Opopona Alayapupọ, lọna Oyero, n’Ijoko. Tosin ni wọn lo n gbe Ojule kejidinlaaadọsan-an (168), Ọna Nasco, ni Ijoko.
Lara nnkan ija oloro ti wọn fi n jale, ti wọn ba lọwọ wọn ni ibọn pistol kan, katiriiji ọta ibọn ti wọn ti yin ateyi ti wọn ko ti i yin mẹta, pẹlu ọkada Bajaj kan ti wọn n gun lọ si oko ole wọn.
Wọn lawọn afurasi tọwọ ba yii ti jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe loootọ lawọn n digunjale, ati pe Desmond lolori awọn.
Ṣa, Ganzallo lawọn ti taari wọn sọdọ awọn ọlọpaa ẹka ti Sango, ki wọn le foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.