Iya Mohbad pariwo: Ẹ gba mi o, awọn kan n lepa emi mi, wọn fẹẹ pa mi o

Monisọla Saka

Iya to bi gbajumọ ọkunrin olorin taka-sufee ilẹ wa to ku lọdun to kọja nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, tawọn eeyan mọ si Mohbad, ti kegbajare sijọba atawọn ọmọ Naijiria lati gba a lọwọ baba ọmọ rẹ ati obinrin kan ti wọn n pe ni Bukky Jesse, ti wọn n tọpinpin oun kiri, ti wọn si n fawọn eeyan ṣọdẹ oun kaakiri.

Ninu fidio kan ti mama yii ṣe to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti n sunkun, to n rawọ ẹbẹ sawọn eeyan pe ki wọn ma wo oun niran, ki wọn ma si jẹ ki wọn ran oun lọ sibi tọmọ oun wa.

O ni, “Gbogbo ọmọ Naijiria, ẹ jọọ, ẹ gba mi, ẹ ṣaanu fun mi o. Bukky Jesse ti polongo ibi ti mo n gbe faye o. Mo dẹ sa fun wọn to o. Ẹ jọọ, ẹ gba mi o. Sanwo-Olu, Mama Rẹmi, ẹ gba mi, ẹ dẹ n wo mi niran. Ẹyin ọmọ Naijiria, ki ni mo ṣe, ẹ gba mi lọwọ Josi o (Joseph).

“Josi, ẹ gba mi lọwọ Josi ati Bukky Jesse, ki ni mo ṣe fun wọn, gbogbo ẹyin abiyamọ ọrun! Igba ti wọn pa ọmọ mi tan, ti wọn tun fẹẹ pa Liam, wọn tun fẹẹ pa mi. Nnkan kan ko gbọdọ ṣe mi o, ko gbọdọ ṣe mi, ko gbọdọ ṣeyawo ọmọ mi, ko gbọdọ ṣe Adura, ko gbọdọ ṣe Liam.

“Ẹ ṣaanu fun mi o, wọn ti fun mi gbẹ, wọn ti fẹẹ pa mi o, Bukky Jesse ti gbe ile ti mo n gbe sori afẹfẹ. Bi mo ṣe n lọ, bi mo ṣe n bọ, ni Bukky Jesse n gbe sori ayelujara. Ẹ ṣaanu mi o, ibi ti Bukky Jesse wa, nnkan kan o gbọdọ ṣe mi, ko gbọdọ ṣe Liam, ko gbọdọ ṣe Adura ati Ọmọwumi o. Gbogbo ọmọ Naijiria, ẹ gba mi, iya ni wọn fi n jẹ mi yii, ẹ ṣaanu mi. Igba ti Mohbad wa laye, o ni ka ma pariwo, igba ti wọn pa a tan bayii, ṣe ẹ ti ri i.

“Wọn ti fẹẹ pa mi o. Bukky Jesse ti fẹẹ pa mi. Niṣe lo ni ki wọn maa ṣọ mi kiri, mi o le rin, ẹru n ba mi. Gbogbo mọto oriṣiiriṣii lo maa n tẹle mi, awọn eeyan maa kun iwaju ile mi bayii, mi o mọ pe emi ni wọn n wo. Emi ni wọn wa n wo, emi ni wọn n wa kiri. Ẹ gba mi, ẹ ṣaanu mi o. Mi o leeyan kankan, ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ gba mi o, mo ni Ọlọrun o, mo dẹ ni yin. Ẹ ṣaanu fun mi. Baba Sanwo-Olu, ṣaanu mi, ẹ ṣaanu mi o”.

Bo tilẹ jẹ pe gbajugbaja oṣerebirin onitiata ilẹ wa to ti n ṣakitiyan lojuna ati le gba idajọ ododo lori iku Mohbad, Iyabọ Ojo, sọ si ọrọ yii. O lohun to nira gidi gan-an ni, nitori oun ti bọ’pa bọ’sẹ ninu ọrọ Mohbad, amọ to jẹ bi mama naa ṣe pe oun laaarọ kutu lati ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ loun ṣe pariwo ọrọ naa sita.

Labẹ ọrọ ti mama yii sọ ni Iyabọ Ojo naa ṣalaye ara ẹ si, to si tun ke si ijọba. O ni, “Laaarọ kutu oni ni mo gba ipe lati ọdọ Iya Mohbad nitori aabo ara wọn, eleyii si ko ọpọlọpọ ibanujẹ ba ọkan mi. Bo tilẹ jẹ pe mo ti gbiyanju lati yẹra lori ọrọ wiwa idajọ ododo fun Mohbad. Mi o le kọ’ti ikun si ariwo iranlọwọ mama yii. Mo lero pe akoko ti to wayi, ti awọn alaṣẹ tọrọ kan yoo kẹsẹ bọ’nu ọrọ yii, ki nnkan too bajẹ, ti ko ba tiẹ ti i bọ sori gan-an.

“Mo nigbagbọ pe a ni ofin lorilẹ-ede yii, mo si gbagbọ pe gbogbo ọmọ Naijiria lo lẹtọọ lati wa lalaafia nile koowa wọn. Gomina wa daadaa, Babajide Sanwo-Olu, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi, ati gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii, ti ọrọ naa ba kan, ẹ jọọ, opin ni lati de ba ọrọ yii.

“Iya yii ti padanu ọmọ rẹ, mo si ro pe ko ba dara ki wọn jẹ ko ṣọfọ ọmọ rẹ lalaafia, ki i ṣe pẹlu pakanleke. Wọn o ti i sinkun Mohbad titi di akoko yii, iyẹn gan-an lọtọ to nnkan to n fa ọgbẹ ọkan, nisinyii, wọn tun wa n ṣọ mama yii kiri. Wọn n yẹyẹ rẹ, wọn n dunkooko mọ ọn. Iyẹpẹrẹ Iya Mohbad yii ko gbọdọ jẹ ohun ti a oo faaye gba mọ. O gbọdọ wa sopin”.

Ọmọbinrin kan to maa n sọrọ lori ayelujara ti wọn n pe ni Bukky Jesse lo gbe aworan ile ti Iya Mohbad n gbe sori ayelujara, to si kọ ọ sibẹ pe, ‘‘Kokooko o, Iya Mohbad, ẹ ṣilẹkun, mo ti wa ni siriiti yin (Aderele Street), to wa ni adugbo D Bells, niluu Ọtta, mo waa fun yin niwee ẹsun. O mọ pe mo ti sọ fun ọ pe ma a wa ọ kan’’.

Ọrọ yii lo jọ pe Iya Mohbad ri to fi pariwo sita pe bawo ni obinrin naa ṣe le gbe ile ti oun n gbe ati adirẹsi ibẹ si ori ayelujara fun gbogbo eeyan lati ri. Obinrin yii jẹ ọkan ninu aọn to maa n sọrọ ta ko Iya Mohbad ati iyawo rẹ Ọmọwumi. O wa lara awọn ti Ọba Elegushi fun niwee ipẹjọ pẹlu bo ṣe n sọ pe ọba alaye naa lo ni ọmọ ti Wumi bi fun Mohbad.

Ko ti i ṣeni to mọ ibi ti ọrọ naa maa ja si.

Leave a Reply