Kayeefi! Baale ile gun iyawo rẹ pa nitori ti iyẹn ge e jẹ lasiko ti wọn n bara wọn sun

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọrọ baale ile kan, Ọgbẹni Marcos Paulino, to fọbẹ kan gun iyawo rẹ, Oloogbe Tatiele-de-Cassia, ẹni ọdun mejidinlogoji pa laipẹ yii, ṣi n ya awọn to gbọ lẹnu. Niṣe lo gun iyawo rẹ pa nitori tiyẹn ge ọwọ rẹ jẹ lasiko tawọn mejeeji n bara wọn sun lọwọ nile wọn to wa lagbegbe Caconde, niluu Sao Paulo, lorileede Brazil.

ALAROYE gbọ pe inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, ni awọn tọkọ-taya ọhun pade, lẹyin tọrọ si wọ laarin wọn ni wọn jọ n gbe pọ loṣu Kin-in-ni, ọdun yii, gẹgẹ bii tọkọ-taya.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Sao Paulo, lorileede Brazil, Ọgbẹni Joao Delfino, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni Paulino waa jọwọ ara rẹ silẹ fawọn ọlọpaa agbegbe naa lẹyin nnkan bii ọjọ meji ti wọn ti n wa a fẹsun iwa ọdaran ti wọn fi kan an.

Ọdọ awọn agbofinro ọhun ni Paulino ti jẹwọ pe lasiko tawọn mejeeji n bara awọn lajọṣepọ lọwọ ni oloogbe naa ṣeeṣi ge oun jẹ, ṣugbọn lẹyin tawọn ṣe e tan ti oloogbe naa n sun lọwọ loun mu egboogi oloro Kokeeni yo kẹri, lẹyin eyi loun ṣẹṣẹ  lọọ mu ọbẹ kan jade ninu kiṣini, toun si gun un yannayanna titi to fi ku patapata.

Leave a Reply