Agbofinro ti n rufin: Ọwọ tẹ ṣọja meji ti wọn lọọ ji waya ina ileeṣẹ Dangote ka

Adewale Adeoye

Ọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Eko ti tẹ ṣọja meji kan, CPL Innocent Joseph ati CPL Jacob Gani bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn lọ sinu ọgba ileeṣẹ Dangote, nibi ti wọn ti n fọ epo bẹntiroolu niluu Eko, wọn si ji awọn waya ina nla ka nibẹ. Lasiko ti wọn n gbiyanju lati gbe awọn waya ọhun bọ sita ni ọwọ tẹ wọn, ti wọn si fa wọn le ọlọpaa agbegbe naa lọwọ pe ki wọn maa ba wọn ṣẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

ALAROYE gbọ pe lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni awọn ṣọja meji ọhun wọnu ọgba ileeṣẹ Dangote, ti wọn si ji waya ọhun ko. Inu mọto Acura Jeep kan ti nọmba rẹ jẹ ‘LAGOS JJJ 594 HS’ ni wọn ko awọn waya ti wọn ji ka naa si, ṣugbọn ọwọ awọn ẹṣọ inu ọgba ọhun tẹ wọn.

Atẹjade kan tawọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede Naijiria, ẹka tipinlẹ Eko fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ  pe, ‘’Wọn mu awọn ṣọja meji kan, CPL Innocent Joseph ati CPL Jacob Gani, ninu ọgba ileeṣẹ Dangote, nibi to ti n fọ epo bẹntiroolu, wọn ba waya ina nla lọwọ wọn, wọn sọ pe wọn lọọ ji i ka ni. Ẹni kẹta wọn, Ọgbẹni Smart, ti sa lọ, ṣugbọn awọn ọlọpaa ṣi n wa a bayii.

Ọdọ awọn ọlọpaa ti wọn wa lawọn ṣọja naa ti jẹwọ pe loootọ awọn lawọn lọọ ji awọn waya ina ọhun ka ninu ọgba ileeṣẹ Dangote, ko too di pe ọwọ tẹ awọn.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti lawọn maa too ṣedajọ lori wọn laipẹ.

Leave a Reply