Ẹwọn n run nimu ọmọkunrin yii, ayederu owo Naira ni wọn ba lọwọ ẹ

Adewale Adeoye

Nitori ayederu owo Naira ti wọn ba lọwọ rẹ, awọn ọlọpaa agbegbe Abakaliki, nipinlẹ Enugu, ti mu ọmọkunrin kan,  Mmaduabuchi Okonkwo, ẹni ọdun mẹrinlelogun, lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Monologu, ni Emene, niluu Enugu, ni Okonkwo ti wa, ṣugbọn lagbegbe IMT, niluu Abakaliki, nipinlẹ Enugu, lọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ.

Dẹrẹba mọto akero kan to wọ lo nawo naa fun, ṣugbọn ti iyẹn taku pe ayederu owo Maira lo na f’oun.  Ọrọ yii dija laarin awọn mejeeji, lawọn agbofinro to n ṣiṣẹ lẹgbẹẹ titi ba da si i, wọn yẹ ara rẹ wo, ni wọn ba ri ẹgbẹrun lọna ogoji Naira to jẹ ayederu lọwọ rẹ.  Loju-ẹsẹ ni wọn ti fọwọ ofin mu un ju sahaamọ.

Laiko ti wọn n fọrọ po o nifun pọ lo jẹwọ pe ẹgbẹrun mẹwaa Naira loun san fun ọgbẹni kan tawọn ọlọpaa lawọn n wa bayii ko too di pe o ko ẹgbẹrun lọna aadọta Naira to jẹ ayederu f’oun, o loun ti na ẹgbẹrun mewaa lara owo naa fawọn kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Daniel Ndukwe, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ọdọ awọn ọlọpaa agbegbe naa ni Okonkwo wa, awọn si maa foju rẹ bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply