O ṣẹlẹ! Lẹyin ti alaṣẹwo gbowo iṣẹ ẹ tan lo ji dukia onibaara rẹ

Adewale Adeoye

Iwaju Onidaajọ Simon Kandiyero, tile-ẹjọ giga kan to wa lagbegbe Harare, lorileede Zimbabwe, ni wọn foju obinrin alaṣẹwo kan, Tafadzwa Bandare Moyo, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn ba. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ji dukia onibaara rẹ kan, Ọgbẹni Tinashe Gabilo, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, lẹyin tiyẹn ba a sun tan lọjọ naa.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aṣaale ọjọ ketadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni Gabilo lọọ ba Moyo l’Ojule karun-un, Msasa Park, laduugbo Nelson-Mandela, pe ko jẹ kawọn jọọ ṣere ifẹ.  Moyo ni ko san dọla mẹwaa, lẹyin ti Gabilo si sanwo naa tan ti wọn jọọ ṣere ifẹ  ni Moyo ba tun ni ko san aadọta dọla owo mi-in f’oun, leyii to yatọ si adehun ti wọn jọ ṣe tẹlẹ.

Nigba ti Gabilo ko sanwo naa fun un nija nla bẹ silẹ laarin awọn mejeeji, ki Gabilo si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, Moyo ti gbe ẹrọ kọmputa alaagbeletan ati foonu igbalode rẹ lọ.

Ko pẹ lẹyin ti aṣẹwo yii ji awọn ẹru naa tan to tun fi lọọ pe ọrẹ rẹ kan, Bandare, ti wọn si tun ji owo atawọn dukia Gabilo lọ.

N ni ọkunrin to ba alaṣẹwo sun ọhun na lọọ fọrọ naa to wọn leti ni teṣan ọlọpaa agbegbe naa. Eyi lo mu kawọn ọlọpaa lọọ fọwọ ofin mu un nile rẹ, ti wọn si foju rẹ bale-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Ọlọpaa olupẹjọ, Miriro Matovo, to foju aṣẹwo ọhun bale-ẹjọ sọ ni kootu pe iwa aidaa ni Moyo hu, ti ijiya si wa fẹni to ba ṣe bẹẹ lawujọ wọn.

Olujẹjọ  ati ọrẹ rẹ lawọn ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Adajọ ile-ẹjọ ọhun ju wọn sẹwọn, o sun igbẹjọ si ọjọ keji, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

 

 

Leave a Reply