Idajọ oju-ẹsẹ: Nibi ti gende yii ti n ji waya ina ka ni ina ẹlẹntiriiki pa a si

Adewale Adeoye

Ọmọkunrin ole kan ti gba idajọ oju-ẹsẹ pẹ̀u bo ṣe fi iku gbigbona ṣefa jẹ lasiko to n ji waya ina mọnamọna ileese ‘Benin Electric Distribution Company’ (BEDC) ka. Niṣe ni ina ẹlẹntiriiki gbe e, to si ku patapata.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, loju ọna marosẹ Airport road, niluu Benin-City, nipinlẹ Edo. Awọn araalu kan ni wọn ri oku gende naa nibi ti ina ẹlẹmtiriiki pa a si. O ti ge awọn waya ina kọọkan silẹ, awọn mi-in lo n ge lọwọ tileeṣẹ to n pese ina mọnamọna fawọn araalu fi muna de lojiji, ni ina ba gbe e, loju-ẹsẹ ni ina ọhun pa a patapata.

Epe lọpọ olugbe agbegbe ọhun n gbe e ṣẹ pẹlu bo ṣe fẹẹ sọ wọn sinu okunkun biribiri pẹlu iṣẹ buruku to n ṣe yii.

Abilekọ Evelyn Gbiwen ti i ṣe ọkan lara awọn ọga agba ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna fawọn araalu  to fidi iṣẹle ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ibanujẹ nla gbaa niṣẹlẹ ọhun jẹ, nitori pe aimọye igba lawọn ti kede rẹ fawọn araalu pe ki wọn yee ba dukia ati irinṣẹ awọn jẹ laarin ilu naa.

O waa rọ awọn eeyan ọhun pe ki wọn maa tete lọọ fọrọ awọn ti wọn ba mọ pe wọn n ba dukia ileeṣẹ to n pese ina mọnamọna jẹ fawọn agbofinro agbegbe wọn.

 

Leave a Reply