Ọjọgbọn Temitọpẹ ti Fasiti Ilọrin ṣawari fifi eepo ẹyin adiẹ peṣe diisu

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọgbọn-binrin kan to n ṣiṣẹ olukọ ni ileewe giga Fasiti Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lẹka ti wọn n pe ni Chemical Engineering, Temitọpẹ Elizabeth Ọdẹtoye, ti ṣawari pipeṣe epo diisu latara eepo ẹyin adiẹ.

Nigba to n ba awọn oniroyin ṣọrọ nipa aṣeyọri rẹ yii niluu Ilọrin, Ọjọgbọn Ọdẹtoye ni oun ṣamulo ọgbọn imọ ati oye oun nibaamu pẹlu igbiyanju Fasiti Ilọrin lati mu idagbasoke ba eto ọrọ-aje orile-ede Naijiria nipaṣẹ lilo imọ ijinlẹ labẹle.

O ṣalaye pe kinni naa wa si imuṣẹ nipaṣẹ iṣamulo imọ kan ti wọn n pe ni ‘transesterification” (iyẹn ṣiṣe apopọ epo tabi ọ̀rá pẹlu ogogoro) lati fi dan an wo. O ni eyi tumọ si pe eepo ẹyin jẹ oun to rọrun ju lọ, ti ko si wọn, lati maa fi peṣe diisu, ti yoo si tun buyi kun awọn olohun ọsin adiẹ, ko si tun ni i jẹ ki eepo ẹyin maa ṣofo lawọn ileeṣẹ ti wọn ti n sin adiẹ.

Ọdẹtoye, ni ṣiṣe amulo eepo ẹyin yii yoo tun jẹ ohun miiran lati fi rọpo diisu ni orile-ede Naijiria.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ti wọn ba bẹrẹ si i ṣamulo diisu yii ni ọpọku-ọyọku, yoo jẹ ki gbogbo ayika orile-ede yii maa mọ toni-toni, ti yoo si mu irọrun ba ilera awọn araalu.

 

Leave a Reply