Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Lati nnkan bii oṣu meji sẹyin lọkan-o-jọkan rogbodiyan ti n waye niluu Okitipupa, latari ija agba to n fi igba gbogbo ṣẹlẹ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan niluu ọhun, ninu eyi ti ọpọ ẹmi awọn eeyan sọnu si.
Iṣẹlẹ yii lo ṣokunfa bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Oyeyẹmi Oyediran, ṣe ko awọn agbofinro kan lọ siluu ọhun lati lọọ ṣeto bi alaafia yoo ṣe jọba.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe akitiyan awọn ẹṣọ alaabo ọhun so eeso rere pẹlu bọwọ wọn ṣe tẹ meji ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ọhun ati ẹnikan ti wọn lo jẹ baba isalẹ wọn.
Ọlabomunde Michael ẹni ogun ọdun, ati Mathew ThankGod, ọmọ ọdun mejidinlogun, la gbọ pe ọwọ awọn agbofinro kọkọ tẹ nibi ti wọn fi ṣe ibuba, awọn mejeeji ni wọn ṣe atọna bi ọwọ ṣe pada tẹ ẹni kẹta wọn, iyẹn Ọlalẹyẹ Sẹgun, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.
Iṣẹ agbẹdẹ ni wọn ni Sẹgun n ṣe ni tirẹ, oun lo si n ṣeto awọn nnkan ija oloro tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fi n pa ara wọn bii ẹran.