Olu Kọbapẹ naa ti waja o

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Olu ilu Kọbapẹ, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, Ọba Olufẹmi Taylor, ti waja.

Ọsan ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila, ọdun 2021 yii, ni Oloye Oluṣẹgun Ọṣọba to jẹ Oluwo Ọba, fi atẹjade kan sita, nibẹ lo ti sọ ọ di mimọ pe pẹlu aṣẹ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, oun kede ipapoda Olu Kọbapẹ, Ọba Olufẹmi Taylor.

Oloye Ọṣọba tẹsiwaju ninu atẹjade to fọwọ si naa pe eto ti n lọ lori bi wọn yoo ṣe maa ṣakoso Kọbapẹ, iyẹn lasiko ti kabiyesi ibẹ ti waja yii.

Igbakeji ọga agba pata ni kabiyesi to waja yii ninu iṣẹ aṣọbode ilẹ wa, iyẹn ko too jọba.

Ipo igbakeji ọga agba pata naa lo fẹyinti si.

Tẹ o ba gbagbe, ọba meji lo waja nipinlẹ Ogun lọsẹ to kọja yii, iyẹn Olowu tilu Owu, ọba Adegboyega Dosunmu, ati Oniwaasinmi tilu Waasinmi, Ọba Babatunde Emmanuel Ọṣuntoogun, ki Olu Kọbapẹ naa too tun lọọ ba wọn bayii.

Leave a Reply