Ijẹbu onitiata kọle olowo nla s’Ikorodu

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Orin, ‘ẹ ba mi dupẹ Oluwa ti ṣe e’ ni oṣere tiata nni, Ọlatayọ Amọkade, tawọn eeyan mọ s’Ijẹbu n kọ lasiko yii pẹlu bo ṣe pari ile onimiliọnu lọna aadọta naira ( 50m), eyi to ti bẹrẹ lati ọdun to kọja.

Ninu alaye t’Ijẹbu ṣe fun ALAROYE lo ti jẹ ko di mimọ pe ilu Ikorodu, nipinlẹ Eko, loun kọle naa si.

Ile naa ki i ṣe ile oloke, ṣugbọn rekete lo ri bii aafin ọba pẹlu awọ to rẹwa gidi ti oṣere ọmọ Ijẹbu Iliṣan naa fi kun un.

Nigba to n dahun ibeere wa pe ṣe nidii iṣẹ tiata naa lo ti rowo kọle nla yii, Ijẹbu sọ pe gbogbo iṣẹ toun n ṣe loun pa owo ẹ pọ.

O ni awọn iṣẹ bii tiata, adari eto lode ariya pẹlu iṣẹ aṣoju awọn ileeṣẹ (Ambassadorial deals) loun fi pari ile naa. O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn ẹbi oun fun atilẹyin wọn to jẹ ki iṣẹ ile naa pari bayii.

Ijẹbu waa ni kawọn eeyan maa reti iṣile oun, o ni ki i ṣe pe oun yoo kan ko wọle naa bẹẹ, oun yoo ṣe pati ti aye yoo gbọ rẹpẹtẹ ni.

Leave a Reply