Ẹ woju awọn ọrẹ meji yii, ayederu ọili ni wọn n ṣe, ladajọ ba ju wọn sẹwọn ọdun mẹrin l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Arikọgbọn ati abamọ nibi tọrọ awọn afurasi ọdaran meji tẹ ẹ n wo ninu fotọ yii, Uche Johnson ati Kingsley Mokete, ja si latari bile-ẹjọ ṣe ju wọn sẹwọn ẹwọn ọdun mẹrin, latari pe wọn jẹbi ṣiṣe ayederu epo ẹnjinni mọto, ti wọn tun pe ni ‘ọ́ìlì àbùrọ’ l’Ekoo.

Ile-ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko nidajọ naa ti waye lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.  Ẹsun mẹrin ọtọọtọ ni wọn fi kan awọn olujẹjọ naa.

Lara ẹ ni pe wọn n ṣe adalu ati agbelẹrọ ọili, wọn n tọju ẹ pamọ, wọn si n pin in kiri fawọn onibaara wọn, leyi to lodi sofin ijọba, bẹẹ ni wọn ko niwee aṣẹ lati ṣe iru okoowo bẹẹ, awọn kan n fi i ṣe jẹun-jẹun ni tiwọn ni.

Ajọ to jẹ tijọba apapọ kan (Standard Organisation of Nigeria, SON), to n ri si ipese nnkan eelo nilẹ wa lo wọ awọn afurasi naa lọ sile-ẹjọ, wọn ni awọn ka wọn mọ ibi ti wọn ti n ṣe adalu ati aburo ọili ẹnjinni mọto.

Igba ti wọn si lọọ ṣayẹwo kinni naa, ko kunju oṣuwọn, ọili buruku gbaa ni. Durọọmu mejidilaaadoje (138) ayederu ọili ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

Wọn lohun ti wọn ṣe yii ta ko abala ki-in-ni ati ikeji, isọri kẹjọ iwe ofin oniruuru aṣemaṣe tijọba apapọ (Miscellaneous Offences), tọdun 2004.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu ki-in-ni, ọdun to kọja, lawọn afurasi naa kọkọ fara han nile-ẹjọ, ṣugbọn wọn lawọn ko jẹbi rara, wọn ni ọili tawọn ki i ṣe feeki, iwe aṣẹ nikan lawọn ko ti i gba.

Eyi lo mu ki wọn pẹ lahaamọ tile-ẹjọ fi wọn si, ti wọn fi raaye ṣayẹwo lakọtun si eroja ti wọn po pọ di ọili ọhun, eyi to pada ja si pe ayederu ni.

Agbejọro olupẹjọ, Amofin Joseph Ọlọfindare rọ ile-ẹjọ lati fawọn afurasi naa jofin ọbayejẹ, tori ewu nla ati ipalara ti ko mọ niwọn ni eroja ti wọn n pin kiri ọhun ti maa ṣe fawọn araalu ti ko mọyatọ ọili kan si omi-in.

Awọn afurasi naa pada jẹwọ pe awọn jẹbi nigba ti adajọ tun bi wọn leere lẹẹkeji.

Adajọ Olurẹmi Oguntoyinbo sọ pe pẹlu bawọn mejeeji ṣe jẹwọ, ti wọn si gba pawọn jẹbi yii, ki wọn sare lọọ lo ọdun meji meji, fun ọkọọkan ẹsun ti wọn fi kan wọn.

O ni ti wọn ba pada de, iṣẹ gidi ni ki wọn mu ṣe, ki wọn yee ṣayederu ọja tori ati jẹun mọ. 

About admin

Check Also

Tori pe wọn yinbọn paayan meji, afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun meje dero ahamọ l’Abẹokuta

Gbenga Amos, Abẹokuta Lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un yii, lawọn gende mẹrin …

Leave a Reply

//ugroocuw.net/4/4998019
%d bloggers like this: