Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọwọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogun kan to porukọ ara rẹ ni Ibrahim Sanni, ẹni ti wọn lo mọ nipa ọpọlọpọ ijinigbe to n waye niluu Akurẹ ati agbegbe rẹ.
Ọmọ bibi ipinlẹ Niger ni Ibrahim gẹgẹ bi alaye to ṣe fun wa, ọdun karun-un si ree to ti dero ilu Akurẹ nibi to loun fi ṣebugbe.
Iṣẹ tomaati títa nikan lawọn eeyan ro pe ọkunrin naa n ṣe, laimọ pe ṣe lo kan n fi eyi boju kawọn eeyan ma baa fura si i pe iṣẹ ajinigbe gan-an lojulowo iṣẹ to yan laayo ju.
Awọn marun-un ni wọn jọ n ṣiṣẹ ibi naa, gbogbo wọn lọwọ si kọkọ tẹ ki awọn yooku too raaye sa mọ awọn Amọtẹkun lọwọ lọjọ ti wọn mu wọn, to si waa ku Ibrahim to jẹ olori wọn nikaawọ awọn ẹsọ alaabo.
Laipẹ yii lọwọ wọn tun tẹ ọmọbìnrin kan ta a forukọ bo laṣiiri. Ibrahim funra rẹ jẹwọ pe loootọ ni gbogbo awọn fi tipatipa ba ọmọ ọlọmọ lo pọ lẹyin tawọn ji i gbe tan.
Ọmọkunrin ọdaran ọhun ni ki i ṣe ibi kan naa loun atawọn ti wọn sa lọ naa ti wa, o ni agbegbe Road Block, l’Akurẹ, lawọn ti ba ara awọn pade lọdun diẹ sẹyin.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alakooso agba fun ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ ni ko si ani-ani pe ọdaran paraku ni Ibrahim.
O ni funra rẹ lo fọ foonu ara rẹ mọlẹ lasiko ti wọn fẹẹ mu un ki ọpọ aṣiri iṣẹ ibi to n ṣe ma baa tu.
Adelẹyẹ ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa, ọdaran ọhun lo ni ko ni i sai foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii awọn ba pari.