Ẹ woju Pasitọ Adetokunbọ to jiiyan gbe ninu ṣọọṣi ẹ ni Ṣagamu, o ni koun le rowo ẹran Ileya fawọn alaini ni

Kayeefi ni ọrọ naa jẹ o. Ohun to si ṣe jẹ kayeefi ni pe pasitọ ni ọkunrin yii, Pasitọ Adetokunbọ Adenọpọ, ki i ṣe musulumi rara. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa mu un pe ajinigbe ni, o ji Ekpo gbe ni Ṣagamu, ti wọn si fi han ni gbangba niluu Abuja, o ni loootọ lawọn ji ọkunrin naa gbe, ṣugbọn nitori koun le rowo toun yoo fi ra ẹran Ileya, apo irẹsi bii meloo ati awọn nnkan mi-in bẹẹ fawọn alaini lasiko ọdun Ileya yii ni.

Ọmọ ọdun mejilelaaadọta (52) ni Pasitọ Adenọpọ, oun lo si da ṣọọṣi kan ti wọn n pe ni New Life Church silẹ ni Ṣagamu, ninu ṣọọṣi ẹ yii naa ni wọn si ti ji Jonathan Ekpo gbe, iranṣẹ kan lati ileeṣẹ ọlọja nla. Adenọpọ ra ọja lọwọ ileeṣẹ yii ni, o si ni ki wọn ba oun mu ọja naa wa sile. Ekpo ni ileeṣẹ rẹ paṣe fun pe ko mu ọja naa lọ sibẹ. Ṣugbọn ki Ekpo too de, Pasitọ yii ti sọ fun awọn ọmọlẹyin ẹ kan pe ti Ekpo ba ti de, awọn yoo ji i gbe ni o, awọn yoo si fi i gba owo nla lọwọ ileeṣẹ rẹ.

Bayii lo jẹ nigba ti Ekpo gbe ọja de fun Pasitọ Adenọpọ, awọn ẹmẹwa ẹ yii, Wiiliam, Linus ati Chris, ra Ekpo mu lati ẹyin nibi to ti fẹẹ gbe ọja to waa gbe fun pasitọ sori tabili, kia ni Pasitọ funra ẹ si ti yọ abẹrẹ kan, lo ba gun Ekpo, niyẹn ba sun lọ. Ni wọn ba wọ ọ lọ si ajaalẹ to wa nisalẹ ṣọọṣi yii, ibẹ lo si wa titi tawọn ọlọpaa fi waa gba a silẹ, nibi tawọn Pasitọ yii ti n beere owo lọwọ ileeṣẹ wọn.

Ohun tawọn ti wọn gbọ nigba ti ọkunrin Pasitọ yii n rojọ niwaju awọn oniroyin n beere ni pe, ki lo kan Pasitọ pẹlu ọdun Ileya, abi iru awọn asọnilẹnu wo ree!

Leave a Reply