Edward ṣeto ijinigbe funra ẹ, o fẹẹ fi gbowo nla lọwọ awọn obi ẹ ni Mowe

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ afurasi ọdaran ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Edward Okache. Wọn ni niṣe lọkunrin yii lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọrẹ ẹ mẹrin kan, o ni ki wọn ji oun gbe, ki wọn le dọgbọn gba owo nla lọwọ awọn obi oun, o loun ni bisinẹẹsi kan toun fẹẹ fowo ṣe lori ẹrọ ayelujara.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi lede l’Ọjọruu, ọsẹ yii, o ni ẹgbọn afurasi ọdaran yii, Abilekọ Comfort Okache, lo tẹ ileeṣẹ ọlọpaa laago idagiri, o ni wọn ti ji aburo oun to n bọ lati ilu Calabar si Eko, gbe, adugbo Mowe ni wọn ti gbe e. O lawọn ajinigbe naa ni wọn pe oun lori aago, ti wọn n beere miliọnu mẹwaa Naira (N10m) gẹgẹ bii owo itusilẹ, o ni kawọn ọlọpaa gba oun o.

Kia ni DPO teṣan Mowe, SP Fọlakẹ Afẹnifọrọ, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ ẹ lati lọọ wadii ohun to ṣẹlẹ, ki wọn si doola ẹmi ẹni ti wọn ji gbe naa.

Erin ku, wahala ba ọbẹ, eyi lo mu kawọn ọtẹlẹmuyẹ fọn sinu igbo Orimẹrunmu, to wa lagbegbe ti wọn n sọ ọhun lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa yii. Iṣẹ aṣelaagun gidi si ni wọn ṣe lati fọ igbo naa tuutuu, wọn wa gbogbo kọlọfin ibẹ, nigbẹyin ni wọn ri Edward ninu ile akọku kan nibi ti wọn fokun de e lọwọ ati ẹsẹ si, wọn si ri awọn gende meji, Ernest Asamoah, toun jẹ ọmọ orileede Ghana, ati Uti Isaiah, ti wọn n ṣọ ọ, ni wọn ba mu wọn, wọn si tu ẹni ti wọn de lokun silẹ.

Amọ nigba ti wọn de teṣan, ti iwadii bẹrẹ, awọn gende meji ọhun jẹwọ pe awọn ki i ṣe ajinigbe tootọ o, ọgbọnkọgbọn lawọn da, wọn ni ẹni tawọn de lokun gan-an lo ni kawọn ṣe bẹẹ foun, awọn si jọ gbimọ-pọ pẹlu ẹ ni lati ba a gba owo nla lọwọ awọn obi ẹ, wọn lo loun ti bẹrẹ okoowo kan lori intanẹẹti, oun si nilo owo nla lati fi ṣe e, o ṣetan, owo la a fi i peena owo.

Wọn tun jẹwọ pe awọn ṣi ku, wọn lawọn meji mi-in, Ephraim Anyijor ati Charity Lukpata tawọn jọ jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Yala, nipinlẹ Cross River naa mọ si ọrọ yii, wọn lawọn eleyii ni wọn ṣe atọna Edward de ọdọ awọn.
Awọn ọlọpaa tun dọdẹ awọn meji yii, ọwọ si tẹ wọn, nigba ti oju k’oju, gbogbo wọn ni wọn jẹwọ pe awọn jọ di i ni, aajo owo lawọn ṣe.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti gbọ sọrọ yii, o si ti paṣẹ ki iwadii to lọọrin tubọ waye lori iṣẹlẹ naa. O ni kawọn afurasi yii ṣi wa lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweeran, l’Abẹokuta, lẹyin eyi, ki wọn taari wọn siwaju adajọ.

Leave a Reply