Kwara ni ohun alumọọni to le gbọ bukaata rẹ lai woju ijọba apapọ- Abdullahi

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Oludije dupo gomina ninu ẹgbẹ oselu People’s Democratic Party (PDP), nipinlẹ Kwara, Alaaji Shuaib Yaman Abdullahi, sọ pe ipinlẹ naa ni ohun alumọọni to le maa fi gbọ bukata ara rẹ lai woju ijọba apapọ, ṣugbọn wọn nilo olori ti yoo le ronu lati ṣamulo awọn ohun alumọọni naa.

Yaman Abdullahi, sọ eleyii lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara. O ni oun setan lati ṣe ijọba lara ọtọ toun ba wọle gẹgẹ bii gomina nipa pipese iṣẹ yanturu fawọn ọdọ lẹka iṣẹ agbẹ, ti idagbasoke yoo fi tete de ba Kwara.

O tẹsiwaju pe agbegbe ijọba ibilẹ Baruten ati Kaiama, ni ẹkun Ariwa Kwara, jẹ ilẹ ọlọraa ti wọn le ti maa gbin owu, fulawa ati nnkan ọgbin miiran ti wọn yoo maa fi ṣọwọ si orile-ede miiran, eleyii to ni yoo pese iṣẹ fun awọn ọdọ, ti wọn yoo maa gba owo to nitumọ, ti eto ọrọ-aje ipinlẹ naa yoo si gberu si i. Bẹẹ nijọba yoo maa pawo wọle nipa gbigba owo-ori lọwọ wọn, eyi ni ko ni i jẹ ki Kwara woju ijọba apapọ ko too le gbọ bukaata ara rẹ. O ni ko dara to ki wọn maa woju ijọba apapọ loṣooṣu ki wọn too le gbọ bukaata ara wọn.

Yaman ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti ṣetan lati gba ijọba pada ni Kwara, tori pe ko si idagbasoke kankan ti ẹgbẹ oṣelu APC to n ṣejọba lọwọ mu ba ipinlẹ naa.

Leave a Reply