Ẹẹmeji niyawo mi ṣẹyun to ni fun mi danu, mi o fẹ ẹ mọ-Yinusa

Adewale Adeoye

‘Bi mo ba fun awọn onibaara lowo mi tabi ki n fi ta tẹtẹ, o san ju bi mo ṣe n na an lori iyawo mi ti mi o si ri anfaani kanakan nibẹ lọ. Afi bii ẹni pe mo kowo sọnu lo jọ loju mi bayii nitori iranu iyawo mi yii pọ ju ohun ti mo le maa fẹnu sọ lọ. Ko ni itẹriba kankan, ki i tẹriba fun mi ninu ile. Ẹẹmeji ọtọọtọ lo ti ṣẹyun to ni fun mi danu, bẹẹ emi ni mo da a lokoowo kan ṣoṣo to fi n gberaga si mi. Emi paapaa ko ṣe mọ o, Oluwa mi, ẹ jẹ ki kaluku wa maa lọ layọ ati alaafia bayii’ Eyi lọrọ to n jade lẹnu ọkọ iyawo kan, Ogbẹni Yunisa Abdullahi, to gbe ẹjọ iyawo rẹ, Abilekọ Zainab Abdullahi, wa sile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa l’Ọja Ọba, ni Mapo, niluu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Nigba ti Yunisa n rojọ ohun tiyawo rẹ n foju rẹ ri ninu ile ti wọn jo n gbe, ko too gbe ọrọ rẹ wa siwaju adajọ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ S.M Akintayọ, pe ko b’oun tu igbeyawo ọdun mẹsan-an to wa laarin awọn mejeeji ka loju-ẹsẹ, o ni, ‘‘Ẹranko gbaa niyawo mi yii, igba gbogbo lo maa n fẹsun kan mi pe mo fẹẹ pa oun, bẹẹ ọwọ mi ree, funfun ni, mi o figba kan lepa rẹ ri, oun gan-an ni ko fura si ara rẹ nitori pe olori kikun ni, tinu rẹ lo maa n fẹẹ ṣe nigba gbogbo. Bẹẹ lo si maa n ko abuku ba mi loju ọmọ kan ṣoṣo to bi fun mi. Omọ naa paapaa ti fẹẹ maa huwa ti iya rẹ n hu si mi ninu ile.

‘‘Latigba ta a ti bi ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin wa, ẹẹmeji ọtọọtọ niyawo mi yii ti ṣeyun to ni fun mi danu, ẹ jọọ, Oluwa mi, ẹ gba mi laaye ki n maa ṣetọju ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin igbeyawo awa mejeeji yii, nitori mo mọ daadaa pe iyawo mi yii ko ni i le ṣetọju ọmọ naa daadaa bi mo ṣe fẹ bi ọmọ naa ba wa lọdọ rẹ’’.

Ninu ọrọ Abilekọ Zainab, o gba lati kọ Yunisa silẹ, ṣugbọn o sọ pe ko soootọ kankan ninu ẹsun ti ọkọ oun fi kan oun yẹn rara.

Bakan naa lo sọ pe ki adajo gba oun laaye lati maa ṣetọju ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin awọn mejeeji yii, nitori pe ọkọ oun ko ni i le ṣetọju ọmọ naa, nitori pe oniranu gbaa ni.

Iyaale ile yii ni, ‘‘Ṣe lọkọ mi maa n ko obinrin nigba gbogbo, ki i ṣetọju wa rara ninu ile, agidi la fi maa n rounjẹ ẹẹmeji jẹ, mi o tete mọ rara pe oniranu eeyan bẹẹ ni, afigba to tun fẹ iyawo keji sile lẹyin to fẹ mi sile ti ko si ti i ju bii oṣu mẹta lẹyin ta a fẹra wa.

‘‘Ohun to jẹ kọrọ Yunisa su mi ni pe gbara ti mo ba ti kọ lati fun un lowo lo maa lu mi bajẹ, gbogbo awọn iwa radaradara wọnyii pata lo jẹ ki n sa kuro ninu ile fun un bayii, ti mo si ti n gbe igbe alaafia nibi ti mo wa’’.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ S.M Akintayọ sun igbejọ naa siwaju, o si paṣẹ pe kawọn mejeeji lọọ so ewe agbejẹẹ mọwọ titi digba ti igbẹjọ yoo fi waye lori ọrọ wọn.

Leave a Reply