Ẹẹmeji ọtọọtọ ni Ọlọrun fi han mi pe mo maa di gomina ipinlẹ Ọṣun- Oyetọla

Florence Babasola, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe imọtẹlẹ Ọlọrun ni bi oun ṣe de ipo gomina, nitori ẹẹmeji ọtọọtọ ni Ọlọrun fi ara han oun nipa rẹ.

Nibi ayẹyẹ idupẹ ọdun keji to de ori aleefa, eleyii to waye nileejọsin The Redeemed Christian Church of God, Osun Province 1, Headquarters, Oṣogbo, ni gomina ti sọ pe Ọlọrun gan-an funra Rẹ ni ipilẹ bi oun ṣe de ipo yii.

Oyetọla ṣalaye pe oun ki i riran, ṣugbọn ẹẹmeji loun ni ibapade pẹlu Ọlọrun lọna to yatọ. O ni oun gẹgẹ bii ọmọ Imaamu la ala, to si jẹ pe orin awọn kristiẹni ni oun n gbọ ninu ala naa.

O ni ohun kan ṣoṣo ti oun ranti ninu ala mejeeji naa ni ipari orin ti oun gbọ nibẹ, ohun naa si ni ‘Ileri Oluwa ni lati ṣẹ’, o ni oun ko gbọ orin naa ri laye, afigba ti oun gbọ ọ loju ala.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘Nigba ti ọrọ naa wuwo lọkan mi, mo pe ọrẹ mi kan, mo si sọ fun un nipa orin naa, oniyẹn lo sọ fun mi pe abala keji orin Timi Oshukọya ni, o lọọ ba mi wa awo orin naa, mo si bẹrẹ si i gbọ ọ, nigba yẹn ni iye mi ṣi, mo si mọ nnkan ti Ọlọrun n sọ.

“Ni gbogbo wahala idibo ati ile-ẹjọ lẹyin idibo, orin yii lo fun mi nigboya, mo si dirọ mọ ọn. Nigba ti awọn kan pinnu lati gbẹmi mi lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, Ọlọrun da ẹmi mi si nitori o ni iṣẹ pataki to gbe le mi lọwọ”

Gomina waa rọ awọn araalu lati tubọ maa ti ijọba rẹ lẹyin pẹlu adura ati suuru, nitori gbogbo ileri Oluwa nipa ipinlẹ yii ni yoo ṣẹ patapata.

Leave a Reply