Eemọ! Wọn ka Ibrahim mọ’bi to ti n ba ewurẹ laṣepọ n’Ifọ

Gbenga Amos, Ogun

Aṣiri ọmọkunrin ọmọọdun mejidinlogun kan, Ibrahim Ismaila, ti wọn fẹsun kan pe o n ba ẹranko laṣepọ ti tu niluu Ifọ, ipinlẹ Ogun. Ibi to ti n ṣe ‘kinni’ pẹlu ewurẹ ni wọn ka a mọ, ọwọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun si ti tẹ afurasi ọdaran ọhun.

Ọkunrin kan to n ṣiṣẹ ajorin-mọrin, ti wọn n pe ni wẹda, Ọgbẹni Jimọh Ọpẹyẹmi, lo fẹẹ lọọ ṣiṣẹ kọngila ti wọn gbe fun un nibi ile ti wọn n kọ lọwọ kan ni adugbo Ilu-Tuntun Ọlọrunṣogo, Ajọwa, nijọba ibilẹ Ifọ, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹjọ yii, lo ba kẹẹfin afurasi ọdaran naa nibi to ti kunlẹ ṣẹyin ewurẹ, to yọ nnkan ọmọkunrin ẹ si ẹran ẹlẹran, o si n ba a laṣepọ bii eeyan.
W ọn ni bi Jimọh ṣe ri iran awoyanu yii lo keboosi sawọn aladuugbo ti wọn wa nitosi, ibẹ lawọn gende ati ẹṣọ Amọtẹkun agbegbe naa  ti ya bo Ibrahim, wọn mu oun ati ewurẹ to sọ di iyawo ẹ.
Wọn beere ọrọ lọwọ afurasi naa, ṣugbọn orukọ ẹ lo da, ko le sọrọ, niṣe lo kan n wo bii ori ẹran.

Ọga agba ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, David Akinrẹmi, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ti fa abẹranko-lopọ naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati tubọ ṣe iwadii, ki wọn si gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin.

Leave a Reply