Florence Babasọla
Ọkunrin kan la gbọ pe o ti dagbere faye lasiko ija ilẹ to bẹ silẹ lagbegbe abule Ọbaloogun, nitosi Mokuro, niluu Ileefẹ, lọjọ Wẹsidee.
Iṣẹlẹ naa la gbọ pe o da wahala pupọ silẹ lagbegbe naa, titi kọja sawọn agbegbe bii Sabo, Lagere, Ẹnuwa ati bẹẹ bẹẹ lọ, ti awọn eeyan si bẹrẹ si i sa kijokijo kaakiri.
Bawọn kan ṣe n sọ pe mọlẹbi lawọn abala mejeeji ti wọn n ba ara wọn ja, yo si ti to ọdun kan ti wọn ti n fa wahala lori ilẹ kusa naa, lawọn mi-in n sọ pe awakusa ni wọn, ṣugbọn ti gbolohun asọ wa laaarin wọn lori ọrọ ilẹ ọhun.
Lọwa ti Ifẹ, Oloye Adekọla Adeyẹyem lo fidi rẹ mulẹ pe ẹni kan ku ninu wahala naa lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ, to si ni ọrọ naa ki i ṣe wahala ẹlẹyamẹya rara.
O fi da gbogbo awọn araalu loju pe laipẹ lọwọ yoo tẹ awọn afurasi ti wọn pa ọkunrin naa, ati pe ki onikaluku maa ba iṣẹ rẹ lọ lai si ifoya tabi ikaya soke rara.
Lọwa fi kun ọrọ rẹ pe awọn agbofinro ti wa kaakiri inu ilu, awọn yoo si fọwọsowọpọ lati ṣiṣẹ pẹlu wọn ki aṣiri awọn amookunṣika naa le tu kiakia.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ ni tiẹ pe Komiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti lọ sibi iṣẹlẹ naa lati ri i pe alaafia jọba nibẹ.