N ko kabaamọ rara pe mo kuro lọfiisi gẹgẹ bii igbakeji gomina Ondo-Agboọla

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Mi o kabaamọ rara pe mo kuro lọfiisi gẹgẹ bii igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, ṣe ni mo n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun gbogbo atilẹyin awọn eeyan ti mo rí gba laarin asiko ti mo fi wa nipo.

Eyi lawọn ọrọ to n jade lati ẹnu Ọnọrebu Agboọla Ajayi ninu atẹjade to fi sita, eyi to fi sami si aṣeyọri rẹ gẹgẹ bii igbakeji gomina Ondo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Agboọla ni oun mọ pe ko ṣee ṣe gẹgẹ bii eniyan ki oun pe ni gbogbo ọna, ṣugbọn awọn to yi oun ka gan-an le jẹrii si i pe oun sa gbogbo ipa oun lati ṣiṣẹ sin awọn ọmọ ipinlẹ Ondo lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun 2017, ti wọn ti bura wọsẹ fun oun si ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji, ọdun 2021.

O dupẹ lọwọ Ọlọrun fun anfaani nla to ri gba lati ibẹrẹ dopin asiko to fi wa lori ipo, igbakeji gomina tẹlẹ ọhun tun dupẹ lọwọ ileeṣẹ eto idajọ to gba a silẹ lọwọ awọn to fẹẹ lo ọwọ agbara fun un.

Bakan lo tun fi ẹmi imoore rẹ han si awọn alabaaṣiṣẹ pọ rẹ, awọn oniroyin to n sisẹ fun un, awọn ẹsọ alaabo to n ṣọ ọ atawọn eeyan ipinlẹ Ondo ti wọn fun un loore-ọfẹ lati waa sin wọn fun ọdun mẹrin gbako.

Ni ipari ọrọ rẹ, o rọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo lati mu ẹlẹyamẹya ẹṣin kuro, ki wọn si jumọ gbadura fun iṣọkan ati alaafia orilẹ-ede yii.

Lẹyin eyi lo ki Akeredolu ati igbakeji rẹ tuntun, Lucky Aiyedatiwa, ku oriire iyansipo wọn.

Leave a Reply