Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lọjọ Aiku, Sannde, ọgbọnjọ, oṣu karun-un, ni ọwọ ba ọkunrin yii, John Daniel, ẹni ọdun mejilelogoji, ti wọn lo fipa ba obinrin ẹni ọgbọn ọdun kan lo pọ ni Sango, nipinlẹ Ogun.
Obinrin ti John fipa ba sun lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Sango. O ṣalaye pe ṣọọbu toun ti fẹẹ maa taja loun wa lọ ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ naa.
O ni loun ba pade afurasi yii, o si sọ foun pe oun ni kọntena kan, pe ẹnikan lo gbe e foun. Obinrin naa sọ pe John ni koun kalọ lati wo kọntena ọhun. O ni nigba tawọn de ile rẹ, o ni koun jokoo ni palọ, koun le lọọ pe ẹni to ni kọntena naa wa.
Iyaale ile yii sọ pe ijọloju lo jẹ pe niṣe ni John tilẹkun, lo ba mu igo kan ati irin ṣoṣoro ti wọn n pe ni Screwdriver jade, o si paṣẹ pe koun bọ ẹwu oun kia.
O ni John fipa ba oun sun karakara lẹyin to ti fi lilu ṣe toun.
Ifisun yii lo mu DPO tẹsan naa, CSP Godwin Idehai, ran awọn eeyan rẹ lọ sile John, wọn mu un pẹlu awọn nnkan eelo to fi dẹruba obinrin naa.
Wọn gbe obinrin to ba lo pọ lọ sọsibitu, John paapaa si ti jẹwọ pe loootọ loun fipa ṣe kinni fun un.
Wọn ti taari ẹ sẹka to n ri si ifipabanilopọ, iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹwu.