Monisọla Saka
Ko din ni eeyan marun-un ti wọn ti padanu ẹmi wọn nibi ijamba ọkọ to n gbe epo bẹntiroolu lọ, to ṣadeede gbina ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lagbegbe Ẹ́lẹ́mẹ́, East-West Road, Port Harcourt, nipinlẹ Rivers.
Ọkọ epo to lọọ lari mọ tirela akẹru mi-in, ni wọn ni epo to n gbe lọ danu, to si ṣe bẹẹ gbina lojiji. Ni kete ti ina sọ laarin ọkọ mejeeji to kọ lu ara wọn ni ina ọhun n fo kiri, to si bẹrẹ si i ran mọ awọn ọkọ to to lọwọọwọ latari sunkẹrẹ-fakẹrẹ oju ọna Akpajo-Onne, ti wọn n ṣe lọwọ. ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ina yii ba ọpọlọpọ dukia jẹ.
Ọkunrin kan to ba awọn oniroyin sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun ṣalaye pe, “Ṣe ẹ mọ pe nitori ọna ti ko daa, ko si oju ọna mi-in ti awọn mọto yẹn le sare gba ti wọn fi rárí wọnu ina naa lairotẹlẹ. Ọpọlọpọ awọn eeyan ti wọn wa ninu mọto wọn ti wọn n gbiyanju lati sa jade ni ina mu mọ inu mọto wọn, ti wọn si ku”.
Oju ọna ti wọn n ṣe lọwọ ni pupọ awọn eeyan di ẹbi iṣẹlẹ ijamba ina naa ru.
Wọn ni aijara mọ iṣẹ awọn ti wọn gbe iṣẹ oju ọna fun ati bi wọn ko ṣe ya ọna mi-in sọtọ fawọn eeyan lati gba lo fa a.
Arabinrin Grace Iringe-Koko, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ni, “Lọwọlọwọ bayii, eeyan bii marun-un ti ku. Kọmiṣanna ọlọpaa atawọn eeyan rẹ wa nibẹ lalẹ iṣẹlẹ ọhun lati ri i pe awọn eeyan ko huwa to ta ko ofin”.
Ikọ panapana ileeṣẹ Indorama Petrochemical Company, atawọn panapana ileeṣẹ mi-in lo to bii wakati meji ki wọn too ri ina naa pa.
Gomina Siminalayi Fubara, ti ipinlẹ Rivers, banujẹ lori iṣẹlẹ ijamba ina ọhun, bẹẹ lo da ọpọlọpọ awọn awakọ naa lẹbi pe iwa irufin lo ko ba wọn.
“Ohun to ba ni lọkan jẹ gidi gan-an ni. Ki ọpọlọpọ awọn eeyan wa ti wọn n gba oju ọna yii maa ṣe pẹlẹ. Mo mọ daju pe iṣẹlẹ to ṣee ṣe ko ma waye ni ohun to ṣẹlẹ yii, to ba jẹ pe awọn onimọto ṣe daadaa, ti wọn si tẹle ofin irinna ojupopo. Amọ o ti bọ, ohun to ṣẹlẹ ti ṣẹlẹ. Ibi ta a ba ara wa ree, a óò mọ bi a ṣe le yanju rẹ.”
O fi kun un pe oun ti pa awọn ileeṣẹ ijọba tọrọ kan laṣẹ lati f’oun ẹkunrẹrẹ alaye lori gbogbo nnkan to ṣẹlẹ, ki awọn le mọ bawọn ṣe maa ṣatilẹyin fun mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ lọ, ati lati wa ọna abayọ si awọn dukia to ṣofo, nitori ki i ṣe ẹbi pupọ awọn eeyan to padanu nnkan-ini wọn sibẹ ni.