Ṣẹyin naa ti gbọ ohun ti Baba Mohbad tun ṣe fun iyawo ọmọ rẹ

Adewale Adeoye

Alagba Joseph Alọba ti i ṣe baba gbajumo akọrin nni, Oloogbe Ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad, ti lọọ lẹ iwe kootu mọ ara ile kan ti wọn gbagbọ pe ibẹ ni Wumi Alọba ti i ṣe iyawo oloogbe naa n gbe lati lẹ jẹ ko wa ni igbaradi silẹ fun ayẹwo ẹjẹ fọmọ to n gbe lọwọ, iyẹn Liam.

Igbesẹ ti Alagba Alọba gbe yii wa ni ibamu pẹlu ẹjọ kan ti adajọ ile-ẹjọ Majisireeti kan da niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, lọjọ Aje, Mịndee, ọsẹ to kọja yii, pe ki wọn lọọ lẹ iwe kootu mọ ara ile ti Wunmi Alọba n gbe, iyẹn bi wọn ko ba lanfaani lati fun un niwee naa.

ALAROYE gbọ pe laaarọ kutukutu lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn loọ lẹ iwe kootu ọhun mọ ara ile to n gbe niluu Eko.

Lọọya Monisọla Odumosu, ti i ṣe ọkan lara awọn lọọya to n ṣoju ẹbi Alọba to bawọn oniroyin sọrọ nipa igbese ọhun ni, ‘‘Ofin faaye gba pe ki wọn lọọ lẹwe ipẹjọ tabi iwe kootu mọ ara ile ti olujẹjọ ba n gbe tabi ile ti wọn mọ mọ ọn, gẹgẹ ba a ṣe ti ṣe lori ọrọ naa. Adajọ ile-ẹjọ kan niluu Ikorodu, lo ṣedajọ naa pe ka lọọ fun Wunmi niwee kootu, tabi ka lẹ ẹ mọ ara ile to n gbe, a si ti ṣe bẹẹ laaarọ kutukutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin yii, a n reti pe ki Wunmi tabi lọọya rẹ yọju si kootu lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yi,i lati waa sọ tẹnu wọn lori ayẹwo ẹjẹ ta a fẹẹ ṣe fọmọ ọwọ rẹ.

Ẹbi Alọba lo ran baba oloogbe naa niṣẹ pe ko gbe ẹjọ ayẹwo ẹjẹ ọhun lọ si kootu, ohun ta a n beere ni pe ki wọn jẹ ka a ṣe ayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe naa nileewosan ijọba tabi ti alaadani kan to kunju oṣuwọn laarin ilu.

Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun to kọja yii, ni oloogbe naa ku lojiji. Latigba naa si ni awuyewuye ti n lọ lori iku gbajumọ naa, lara awọn ọrọ tawọn eeyan n sọ ni pe ki Wunmi ti i ṣe iyawo oloogbe naa lọ ṣayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe naa lati mọ boya loooto. Oloogbe Mohbad lo lọmọ ọwọ rẹ. Ori ọrọ yii ni baba oloogbe duro le bayii.

Leave a Reply