Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, (EFCC), ti mu oyinbo Chinese meji kan, Duan Ya Hong ati Xiao Yi, fẹsun pe wọn n wakusa lọna aitọ niluu Bánní, nipinlẹ Kwara.
Ninu atẹjade kan ti EFCC, gbe sori ayelujara lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, to tẹ ALAROYE lọwọ, ni wọn ti ṣalaye pe ọwọ awọn ti tẹ awọn oyinbo Chinese meji kan, Duan Ya Hong ati Xiao Yi, lori ẹsun wiwa ohun alumọọni lai gba iwe aṣẹ lọwọ awọn alaṣẹ fun ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni Ebuy Trading Worldwide Nig. LTD, ti wọn n lo.
O tẹsiwaju pe ajọ naa ti foju awọn oyinbo yii bale-ẹjọ giga tijọba apapọ kan to wa niluu Ilọrin, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.
Ẹsun ta a fi kan wọn ni pe, “Iwọ, Ebuy Trading Worldwide Nig. LTD, Duan Ya Hong, Xiao Yi, nigba kan ri ninu oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lọ si ilu Bánní, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara, lati lọọ ko ohun alumọọni kan bii ọgbọn paali, ti ẹ si fi ọkọ tirela kan to ni nọmba JJJ 386 XT ko o lai gba aṣẹ lọwọ ijọba, leyii to ta ko iwe ofin ilẹ wa, ti ijiya si wa ni abala kin-in-ni, ninu iwe ofin ilẹ wa, tọdun 1984, fẹni to ba ṣ bẹẹ”.