Eyi lawọn ohun to ṣẹlẹ nibi idibo ijọba ibilẹ to waye nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Eto idibo kaakiri ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ Ọyọ, bẹrẹ lọjọ Abamẹta, Ṣatide, ọjọ kẹtadinlọgbọn (27), oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Ẹ̀wẹ̀, ọwọ kekere kọ lawọn oloṣelu fi mu idibo naa, paapaa, pẹlu bo ṣe jẹ pe ọjọ idibo ọhun ko ti i pe rara ti awọn janduku oloṣelu ti bẹrẹ si i ji awọn ohun eelo idibo gbe.

Yatọ si eyi, niṣe lalakooso eto idibo nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ṣaki, Ọgbẹni Nathaniel Ẹniọla, deede poora laaarọ yii, ibi to sa lọ ko ye ẹnikan, bẹẹ ni ko sẹni to ti i gburoo ẹ titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Niṣe lawọn eeyan, paapaa, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), n fẹhonu han nitori bi awọn ohun eelo idibo ti ajọ eleto idibo gbe lọ sibẹ ṣe kere jọjọ.

Ariwo ti awọn olufẹhonu han ọhun si n pa ni pe ko si eto idibo niluu Ṣaki, awọn kò sí ní í gba ki wọn kan deede kede pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan ti wọle idibo nibẹ, nitori ko sẹni to ri ibo di lọdọ awọn rara.

Titi di aago kan ku ogun iṣẹju (12:40) lọsan-an ọjọ Abamẹta ọhun, wọn ko ti i bẹrẹ ibo didi lọpọlọpọ ibùdó idibo nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki ati Iwọ-Oorun Ṣaki.

Gbọingbọin lawọn ọfiisi ajọ eleto idibo (OYSIEC) lawọn ijọba ibilẹ mejeeji si wa ni titi pa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn (25), oṣu yii, lawọn janduku oloṣelu kan kọ lu awọn oṣiṣẹ eleto idibo niluu Okeho, nijọba ibilẹ Kajọla, ni ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ji awọn iwe idibo gbe lọ.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti ta awọn agbofinro agbegbe ijọba ibilẹ Kajọla nibẹ lolobo, ko si pẹ rara tọwọ awọn ọlọpaa fi tẹ mẹrinla ninu awọn to lọwọ ninu iwa madaru naa, ti wọn si ti tun gba gbogbo iwe idibo ti wọn ji gbe naa pada lọwọ wọn.

Ko sẹni to ti i mọ ẹgbẹ oṣelu ti awọn eeyan naa n ṣiṣẹ fun, ṣugbọn ohun to daju ni pe  wọn fẹẹ fi awọn kinni naa dibo fun ẹgbẹ oṣelu tiwọn nikan ni.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Alaga ajọ eleto idibo nipinlẹ Ọyọ, Ọyọ State Independent Electoral Commission (OYSIEC), Aarẹ Isiaka Ọlagunju, fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn kọ lu awọn oṣiṣẹ eleto idibo, ṣugbọn irọ ni pe wọn ji iwe idibo gbe. O ni wọn o ji ohun eelo idibo kankan gbe.

Ọga ọlọpaa agbegbe yẹn ti paṣẹ fun DPO Kajọla pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa pata ni ki wọn mu.

Bo tilẹ jẹ pe idibo ọhun ti bẹrẹ kaakiri ipinlẹ Ọyọ, ọpọ eeyan ni ko jade dibo, awọn eeyan to wa nibudo idibo gbogbo ko to nnkan.

Lara awọn to ti dibo bayii ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde. Ni nnka bii aago mẹwaa kọja iṣẹju mẹẹẹdọgbọn aarọ yii lo ṣe ojuṣe rẹ ọhun nibudo idibo kọkanla, Wọọdu kin-in-ni, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ariwa Ibadan.

Nigba to n sọrọ ni kete to dibo tan, Gomina Makinde fi idunnu ẹ han si eto gbogbo to wa nilẹ nipa eto idibo yii, ati bi eto naa ṣe n lọ wọọrọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Mo rọ gbogbo awọn to ṣi jokoo sile lati jade lọọ dibo, ki wọn le ka awọn naa mọ ara awọn to kopa ninu eto ijọba awa-ara-wa”.

Leave a Reply