Ọlawale Ajao, Ibadan
Lọjọ Abamẹta, Satide to kọja, nikan ṣoṣo, eeyan marundinlaaadọrin (65) lo ko arun Korona nipinlẹ Ọyọ.
Lọjọ yii kan naa nijọba yọnda eeyan mọkanlelaaadọrun-un (91) kuro nibudo ti wọn ti n tọju awọn alarun Korona lẹyin ti wọn ti gbadun.
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade kan to gbe sori ikanni abẹyefò (túítà) rẹ lọjọ Satide to kọja.
Aarin awọn to n gbe igboro ilu Ibadan ni kokoro arun naa ti pọ ju lọ lọtẹ yii, nitori mẹtadinlogun (17) ninu awọn eeyan to lugbadi arun yii lo jẹ ara ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan.
Ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Guusu Ibadan lo tẹle e pẹlu akọsilẹ eeyan mẹtala. Iye eeyan ti ayẹwo fi han pe wọn ti ko kokoro arun ọhun lọjọ naa níjọba ibilẹ kọọkan ni Ila-Oorun Ọyọ (9), Ido (8), Lagelu (7), Oluyọle (6), Oorelope (3), ati Akinyele (3).
Awọn yooku ni Ila-Oorun Ariwa Ibadan (3),Ẹgbẹda (3), Ọna-Ara (2), Atiba (2), Guusu Ogbomọṣọ (2), Isẹyin (2), Ila-Oorun Ibadan (1), Ariwa Ogbomọṣọ (1), Iwọ-Oorun Ọyọ (1), Iwọ-Oorun Ariwa Ibadan (1) ati eeyan kan nijọba ibilẹ Aarin-Gbungbun Ibarapa.
Pẹlu abajade ayẹwo tuntun yii, apapọ eeyan ti Korona ti mu nipinlẹ Ọyọ ti di ọrinlelẹgbẹjọ ati mẹsan-an (1,689) titi dọjọ Satide ọhun.
Apapọ awọn to lugbadi arun Korona tẹlẹ, ṣugbọn ti wọn ti lalaafia bayii jẹ okoolelẹẹẹdẹgbẹrun ati marun-un (925).
Gomina Makinde waa rọ ẹnikẹni to ba ni ailera kan tabi omi-in, paapaa, aarẹ lati inu ara wa, iba, ara hihun, aile mi daadaa ati bẹẹ bẹẹ lọ lati pe awọn eleto ilera lori awọn nọmba ibanisọrọ wọnyi: 08095863000,| 08078288999 tabi 08078288800 tabi ki wọn kan si ileewosan ijọba to ba sun mọ wọn ju lọ.