Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, lawọn eeyan meji mi-in tun gbọna ọrun lọ ninu ijamba ọkọ ni Fidiwọ.
Oju ọna marosẹ Eko s’Ibadan ni Fidiwọ wa. Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, eeyan mẹrin lo ku ninu ijamba ọkọ nibẹ, awọn mejila fara pa. Ohun ti ọga FRSC Ogun, Ahmed Umar, ṣalaye ni pe ni nnkan bii aago mẹta ọsan kọja iṣẹju mọkandinlogun ni ijamba to gbẹmi eeyan meji yii waye.
O ni jiipu Lexus ti nọmba ẹ jẹ AKD 405 AQ lo n sare buruku bọ, to lọọ kọ lu tirela to ni nọmba JJJ 532 XM latẹyin.
Bi dẹrẹba to wa jiipu ṣe da a bo tirela ni ijamba ṣẹlẹ, ti eeyan meji ku loju-ẹsẹ ninu awọn mẹrin to wa nibẹ. Kọmandanti Umar sọ pe ijamba to ṣee dena ẹ ni awakọ jiipu yii jẹ ko waye, to si ṣe bẹẹ pa eeyan meji danu.
Mọṣuari FOS to wa n’Ipara, ni wọn ko awọn to doloogbe naa lọ gẹgẹ bi Umar ṣe wi. O ba mọlẹbi awọn teeyan wọn ku kẹdun, o si ni ki wọn lọ sọfiisi FRSC Ogunmakin fun ẹkunrẹrẹ alaye.