Eeyan meje jona ku nigba ti mọto elero kan gbina lọna marosẹ Ṣagamu-si Benin

Gbenga Amos, Abẹokuta

Eeyan meje, ninu eyi ti alaboyun ati ọmọ kekere wa, ni wọn padanu ẹmi wọn sinu ijamba kan to ṣẹlẹ ni orita Odogbolu, loju ọna marose Sagamu si Benin, lọna Ijẹbu-Ode, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun yii.

Alukoro ileeṣẹ to n mojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun, Trace, Babatunde Akinbiyi, to fi iṣẹlẹ naa lede ṣalaye pe ẹnjinni mọto Mazda elero mejidinlogun naa ti nọmba rẹ jẹ AGL886YD lo gbina nitori apọju epo (engine oil) ti wọn rọ si i.

ALAROYE gbọ pe agbegbe Koṣọfẹ, niluu Eko, ni mọto naa ti n bọ, ibi eto ọlọjọ mẹrin kan ti ẹgbẹ awọn obinrin Musulumi kan ti wọn n pe ni Al Mu’minaat Trainning Forum, ṣagbekalẹ rẹ, eyi ti wọn maa n ṣe lọdọọdun ni awọn eeyan naa n lọ ni abule kan ti wọn n pe ni Odosengolu, nitosi Ijẹbu-Ode.

Akinwumi ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe eeyan mẹẹẹdogun lo wa ninu ọkọ akero naa, meje ninu wọn, ninu eyi ti obinrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Basirat Adebanjọ ati ọmọ rẹ ti ko ju ọdun meji lọ, Abidat, wa, ni wọn jona kọja sisọ nigba ti ina naa ṣẹ yọ lojiji lati ibi ẹnjinni okọ ọhun.

Awọn meje la gbọ pe wọn fara pa yanna yanna ninu ijamba ina ọhun, bo tilẹ jẹ pe nnkan kan ko ṣe dẹrẹba to wa mọto naa.

Dawah Centre, niluu Ijẹbu-Ode, ni wọn ko oku awọn to jona ku ninu iṣẹlẹ naa lọ, nigba ti wọn ko awọn to fara pa lọ si awọn ọsibitu kan niluu Ijẹbu-Ode ati Eko.

Ẹkan to n mojuto igboke-gbodo ọkọ to wa niluu Odogbolu ni wọn gbe mọto ti awọn eeyan ti padanu ẹni wọn ọhun lọ.

Akinwumi waa rọ awọn awakọ lati maa fẹsọ ṣe loju popo.

Leave a Reply