Eeyan meje ku, ọpọ fara pa, nibi jamba ọkọ ni marosẹ Ilọrin si Ogbomọṣọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, eeyan meje lo ku, ti awọn miiran si fara pa, nibi ijamba ọkọ to waye lagbegbe Ọttẹ, ni marosẹ Ilọrin si Ogbomọsọ, lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ to kọja yii.

ALAROYE gbọ pe nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ naa ni ijamba ọhun waye latari ere asapajude ti ọkọ ero Mazda kan ti nọmba rẹ jẹ ZUR 159 XJ sa, to si sokunfa ijamba naa. Eeyan mejidinlọgbọn ni ọkọ naa ko, ti meje, ninu eyi ti ọmọdebinrin meji wa ku lojiji ninu ọkọ naa.
Adari ẹṣọ alaabo oju popo nipinlẹ Kwara, Jonathan Ọwọade, sọ pe taya ọkọ to fọ lo sokunfa ijamba naa. O tẹsiwaju pe gbogbo awọn to fara pa ni wọn ti ko lọ si ileewosan alaadani kan ni agbegbe Gari-Alimi, ati jẹnẹra, niluu Ilọrin, fun itọju to peye. Bakan naa ni wọn ti ko oku lọ si yara igbooku-si nileewosan jẹnẹra yii kan naa.
Ọwọade rọ gbogbo awọn awakọ lati maa tẹ ẹ jẹẹjẹ loju popo, ki wọn yee sare asapajude, ki wọn si ma ko ero akoju, tori ohun lo n fa ijamba naa.

Leave a Reply