Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Eeyan meji lo pade iku ojiji, nigba tawọn mẹsan-an mi-in tun fara pa, ninu ijamba ọkọ to waye niluu Ikarẹ Akoko, n’ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2023 yii.
ALAROYE gbọ pe, ijamba ọhun waye pẹlu bi awọn ọkọ bọọsi akero kan to n bọ lati Abuja ṣe padanu ijanu rẹ nibi kan ti wọn n pe ni Iyana Jubilee, loju ọna Ikarẹ si Ajọwa Akoko, to si ṣe bẹẹ lọọ kọ lu ọlọkada kan atawọn ero to gbe sẹyin lasiko naa.
Diẹ ninu awọn ọlọkada ọhun ni wọn ku loju-ẹsẹ, ti awọn kan ninu awọn ero ọkọ mejeeji si tun ku pẹlu.
ALAROYE fidi rẹ MULẸ lati ọfiisi ajọ ojupopo to wa n’Ikarẹ Akoko pe ni nnkan bii aago meje ku iṣẹju mẹwaa aarọ ni ijamba naa ṣẹlẹ.
Wọn ni awọn eeyan mọkandinlogun ni wọn fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun, awọn meji ku loju-ẹsẹ, nigba ti awọn mẹwaa fara pa kọja sisọ.
Awọn to fara ṣeṣe ni wọn ti ko lọ sileewosan ijọba to wa niluu Ikarẹ Akoko, fun itọju. Mọṣuari ọsibitu yii kan naa la gbọ pe wọn tọju oku awọn ti wọn padanu ẹmi wọn si titi ti awọn ẹbi wọn yoo fi yọju.
mọṣuari ọsibitu yii kan naa la gbọ pe wọn tọju oku awọn ti wọn padanu ẹmi wọn si titi ti awọn ẹbi wọn yoo fi yọju.