Eeyan meji ku, mẹrin fara pa, ninu ijamba ọkọ l’Anthony

Faith Adebọla, Eko

O kere tan, eeyan meji lo doloogbe, tawọn mẹfa mi-in si wa lẹsẹkan aye ẹsẹ kan ọrun ninu ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe Anthony, loju ọna marosẹ Mile 12 si Oṣodi lanaa, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọkọ tipa meji, bọọsi akero kan ati ọkọ tanka ti epo disu kun inu rẹ tẹmutẹmu kan lo fori sọ ara wọn nibi iṣẹlẹ ọhun. Nọmba ọkan lara awọn tipa naa ni OGUN AKM-714-ZT, awọn mẹta yooku ko ni nọmba, tabi ki nọmba wọn ti ja sọnu latari jamba naa.

Ninu alaye kan ti ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, Dokita Olufẹmi Oke-Ọṣanyintolu, ṣe, o ni iwadii awọn ti fihan pe ere asapajude ati wiwa ọkọ niwakuwa lo ṣokunfa ijamba yii.

Olufẹmi ni ijamba naa ha awọn eeyan to wa ninu ọkọ akero naa mọ, igbe oro ati ariwo idaro wọn lawọn n gbọ kikankikan nigba tawọn oṣiṣẹ ajọ LASEMA debẹ, ko si sọna lati yọ wọn. Niṣe ni wọn ṣẹṣẹ lọọ gbe katakata ajọ naa lati fi doola ẹmi awọn to ha sinu iṣẹlẹ ọhun, ki wọn too ri mẹfa yọ laaye, bo tilẹ jẹ pe wọn ti fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii.

Ṣugbọn awọn obinrin agbalagba meji kan ko rọgbọn da si i, wọn ti doloogbe, wọn si ti ko oku wọn lọ si mọṣuari nileewosan ijọba to wa lagbegbe ibẹ.

 

Leave a Reply