Ọlawale Ajao, Ibadan
Eeyan meji ni wọn lo riku ojiji he lasiko ti awọn ọlọkada atawọn alamoojuto ọgba ẹwọn Agodi, n’Ibadan, fija pẹẹta.
Yanpọnyanrin ọhun bẹ silẹ nigba ti awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ọhun lọọ le awọn ọlọkada to maa n to tọọnu niwaju ileeṣẹ naa gbero lati sun siwaju.
Awọn olutaja kan laduugbo ọhun sọ pe bi awọn ọlọkada ṣe n ba wọn ṣagidi lọrọ yii dija, nibi tawọn agbofinro yii si ti n yinbọn lati dẹruba awọn eeyan naa nibọn ti ba ọlọkada kan, to si gbabẹ ku.
“Awọn ọlọkada fẹhonu han lọ siwaju ọgba ẹwọn, nibẹ lawọn ọga ọgba ẹwọn ti yin tíágaàsì, ti wọn si tun yinbọn lati dẹruba awọn to n fẹhonu han. Nibẹ nibọn tun ti ba ẹlomin-in to fi ku.
“Mi o waa mọ boya ọlọkada lẹni ti wọn yinbọn pa tabi ero to n kọja lọ jẹjẹ ẹ.”
Iwaju ileeṣẹ ọgba ẹwọn Agodi lawọn ọlọkada to n gbero Agodi si Iwo Road, si Agodi, si Akobọ, ti maa n to tọọnu lati gbero. Ọpọ igba lawọn ọlọpaa atawọn alamoojuto ọgba ẹwọn si maa n le wọn lati sun siwaju ko too di pe kinni ọhun yọri si gbodo-n-roṣọ laaarọ yii.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni alaafia ti jọba laduugbo naa nitori ni kete ti wọn fiṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti lawọn ọlọpaa pẹlu awọn agbofinro yooku ti lọ sibẹ lati pana rogbodiyan naa.
Ninu ọrọ tiẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn, Ọgbẹni Ọlanrewaju Anjọrin, sọ pe loootọ lede aiyede waye laarin awọn pẹlu awọn ọlọkada, ṣugbọn awọn ko yinbọn rara debi ti eeyan maa ku tabi fara pa.
O ni, “Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ (Operation Burst) ti duro siwaju ileeṣẹ wa lati ri i pe eto aabo ko mẹhẹ.