Monisọla Saka
Eeyan meji lo ti padanu ẹmi wọn, ti awọn mẹrin si fara pa yannayanna nibi ijamba ọkọ to waye laarin mọto Nissan Cabstar ati ọkọ ajagbe Mack kan lagbegbe Iyana Ẹgbado, Itori, lopopona marosẹ Eko si Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022 yii.
Adari ajọ ẹṣọ alaabo oju popo nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Ahmed Umar, lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin l’Abẹokuta. O ni ni deede aago mẹfa aarọ ni ọkọ Cabstar to ni nọmba idanimọ KTU 142 XH lọọ fori sọ tirela nla Mack kan pẹlu nọmba T-12736 LA, ti wọn paaki kalẹ lẹbaa ọna nitori taya ẹ to jo. Loju-ẹsẹ ni meji ninu awọn eeyan meje to wa ninu ọkọ ọhun dakẹ, awọn mẹrin ṣeṣe, eeyan kan ti ori ko yọ ko si fara pa nibi kankan.
Umar ṣalaye siwaju pe awọn ti ko awọn meji ti wọn ku atawọn ti wọn fara pa lọ si ileewosan ijọba to wa ni Ifọ, fun amojuto to peye.
Bakan naa lo ba awọn mọlẹbi tọrọ ṣẹlẹ si kẹdun, o waa gba wọn niyanju lati kan si ileeṣẹ FRSC Itori, fun ẹkunrẹrẹ alaye lori ijamba naa.
Bẹẹ lo tun gba awọn awakọ nimọran lati ma ṣe maa paaki kaakiri eti ọna, o ni ti ọkọ wọn ba yọnu, ki wọn fi awọn ami ti wọn n lo ni oju popo si ibi to yẹ, kawọn mọto to n bọ lọọọkan le ri i.