Eeyan meji, mọto mejila jona gburugburu ni Sango

Gbenga Amos, Abẹokuta

Iran buruku niran to ṣẹlẹ laaarọ kutu Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹwaa yii, bawọn eeyan ṣe n pariwo ‘ikunlẹ abiyamọ’, bẹẹ lawọn mi-in kawọ mọri, latari bi mọto mejila ṣe jona, ti eeyan meji si ba iṣẹlẹ naa rin, ni too-geeti Sango-Ọta, nipinlẹ Ogun, lasiko ti tanka epo kan gbina.

Ọkẹ aimọye  dukia lo ṣofo, ọpọ eeyan si n sa kijokijo ki wọn ma lọọ fara kaaṣa ina buruku to n jo naa. Iṣẹlẹ yii waye ni ọna to gba adugbo Ilo Awẹla jade si titi marosẹ Sango si Abẹokuta, ni ikorita too-geeti Sango, ti ko fi bẹẹ jinna si ẹka ileeṣẹ awọn ẹṣọ ojupopo.

A gbọ pe awọn panapana ti n gbiyanju lati pa ina naa.

Leave a Reply