Eeyan mẹrin ati ọpọlọpọ dukia ṣegbe sinu ijamba mọto n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan mẹrin lo j’Ọlọrun nipe, ti ọpọ ṣi fara pa yannayanna ninu ijanba ọkọ tirela gaasi kan laduugbo Mọkọla, n’Ibadan.

Tanka epo to kun bamu fun gaasi idana to n bọ lati ọna Sango lọ si Mọkọla, lo deede padanu ijanu ẹ, to si kọ lu awọn to n taja lẹgbẹẹ titi pẹlu ọkọ tasin atawọn ọlọkada to n loodu ero nitosi abẹ biriiji ni ikorita Mokọla nibẹ.

Ọkọ Micra mẹfa ati ọkada mẹrin l’ALAROYE gbọ pe o ṣegbe sinu iṣẹlẹ naa.

Ọkan ninu awọn tori ko yọ ninu iṣẹlẹ yii, Ajayi Ibraheem, ṣalaye pe “Inu takisin to n lọ si Challenge ni mo wa lasiko yẹn. Bi mọto wa ṣe n mura lati ṣi ni bireeku tanka gaasi yẹn ja, to kọ lu wa ninu mọto wa.

“Mi o mọ bi mo ṣe jade ninu mọto. Ọlọrun gan-an lo yọ mi ti mọto ko gun mi lori mọlẹ.

“Aanu obinrin kan bayii to pọnmọ ti ko ju ọmọ oṣu marun-un sẹyin lo ṣe mi ju. Niṣe lori ọmọ yẹn fọ silẹ bayii. Nibi tawọn eeyan ti n ba ọmọ yii kaaanu lọwọ ni wọn ti ri i pe iya yẹn ṣi n mi tupetupe ni tiẹ. Bi wọn ṣe sare gbe iya yẹn lọ sọsibitu niyẹn. Mi o waa mọ bo ṣe maa ri lara ẹ nigba to ba ji saye, to gbọ pe ọmọ oun ti ku.”

Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lori iṣẹlẹ yii, oludari ajọ to n doola ẹmi awọn eeyan ninu ijanba oju popo, eyi to wa labẹ ajọ iṣọkan agbaye (UN), Ọgbẹni Oluwarotimi Ajiṣafẹ, fidi ẹ mulẹ pe “Ba a ṣe n wi yii, eeyan mẹrin lo ti ku sinu ijanba yii, eeyan mẹta la sare gbe lọ sileewosan, adura la n ṣe fawọn wọnyẹn pe k’Ọlọeun jẹ ki wọn ye e.

‘‘Ara nnkan ta a maa n sọ niyẹn o, nigba tijọba ba le awọn eeyan pe ki wọn yee taja loju titi, wọn aa tun pada sibẹ bii pe ko si ibomi-in ti wọn ti le rọja ta ju oju titi lọ.”

Ninu ọrọ tiẹ, Alaga ajọ Oyo State Traffic Management Agency (OYRTMA), iyẹn ajọ to n mojuto igbokegbodo awọn ohun irinna nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Adeoye Ayọade, sọ pe eeyan marun-un ni wọn gbe lọ sileewosan fun itọju, nigba ti wọn gbe oku awọn to ba iṣẹlẹ buruku ọhun rin lọ si yara igbokuu-si nileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ, n’Ibadan.

 

 

Leave a Reply