Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹsọ alaabo ara ẹni laabo ilu (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti fidi ẹ mulẹ pe eeyan mẹrin to jẹ mọlẹbi kan naa jẹ majele mọ ounjẹ ni abule Olori, lagbegbe Banni, nijọba ibilẹ Moro, lẹkun Ariwa ipinlẹ Kwara, ti wọn si gba’bẹ lọ sọrun.
Ninu atẹjade kan ti ẹsọ alaabo naa fi sita, ti Alukoro ajọ ọhun nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, buwọ lu sọ pe awọn mẹrẹẹrin ku ni nnkan bii aago meje owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lẹyin ti wọn jẹ majele mọ ounjẹ. O tẹsiwaju pe arakunrin kan, Alhaji Mohammed Abubakar, tilu Olori, lagbegbe Banni
lo mu iroyin naa wa pe awọn ọmọ oun meji; Umar Mohammed, ẹni ọdun marundinlọgbọn, ati Kadir Mohammed, ẹni ọdun mejidinlogun ni wọn n bi ni nnkan bii aago mẹrin idaji Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, tawọn si sare gbe wọn lọ sileewosan gẹnẹra to wa ni ilu Igbẹti. Wọn ṣe ayẹwo fun wọn, ayẹwo fi han pe majele ni wọn jẹ, ti ko si pẹ pupọ ti awọn mejeeji fi ku.
Afọlabi tẹsiwaju pe lakooko ti awọn mọlẹbi n gbaradi lati sin awọn oku meji yii, ni ọkan lara ọmọọmọ Abubakar lọkunrin kan naa tun ku.
Ọkunrin yii ni awọn oṣiṣẹ NSCDC, ti Ọgbẹni Adesina Taofeek ṣaaju kọwọọrin lọ sọdọ awọn mọlẹbi lati lọọ ba wọn kẹdun, bi wọn tun ṣe sọ pe ọmọ ọmọ arakunrin ọhun miiran, Bashiru Mohammed, ti wọn tun sare gbe lọ sileewosan tun ku loju-ẹṣẹ.
Ajọ ẹsọ alaabo NSCDC ti waa gba awọn mọlẹbi nimọran lati lọọ ṣe ayẹwo fun awọn ọmọ to ṣẹku ti wọn jọ jẹ ounjẹ to ni majele ọhun.