Eeyan mẹrin ku sinu ijamba ọkọ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ero mẹrin ni wọn ku sinu ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ lagbegbe Olokuta, loju ọna marosẹ Akurẹ si Ondo, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

Ijamba ọkọ ọhun ni wọn lo waye lẹyin ti awakọ Toyota Sienna kan to n bọ lati ọna Ondo lọọ fori sọ ọkọ bọọsi kan to n na oju ọna Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.

A gbọ pe loju-ẹsẹ lawọn mẹrin ti ku ninu awọn ero to wa ninu ọkọ mejeeji, nigba tawọn mi-in si tun fara pa yannayanna.

Fun bii wakati kan gbako lawọn ọkọ ko fi raaye kọja loju ọna marosẹ ọhun latari iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye naa, awọn eeyan olugbe Olokuta atawọn awakọ ti wọn rin si asiko la gbọ pe wọn gbiyanju ati fa ọpọ awọn ero jade kuro ninu ọkọ ti wọn ha mọ, kawọn ẹṣọ alaabo too de.

Lẹyin-o-rẹyin lawọn ẹṣọ oju popo ṣẹṣẹ de sibi iṣẹlẹ naa, awọn ni wọn si pada ko oku awọn to ku sinu ijamba ọkọ naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ.

Leave a Reply