Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ ipaniyan nipinlẹ Ogun ni ọga ọlọpaa ipinlẹ naa paṣẹ pe ki wọn ko awọn meje tọwọ tẹ pe iṣẹ pipani-ṣetutu-owo ni wọn yan laayo tọwọ tẹ laipẹ yii lọ, ki wọn wadii wọn, ki wọn si gbe wọn lọ sile-ẹjọ kia.
Iwalaaye ọmọlakeji ko nitumọ si awọn eeyan naa, afi ki wọn da ẹmi alaiṣẹ legbodo lojiji, ki wọn si kun ẹya ara rẹ bii ẹran, ki wọn ta a fun etutu ọrọ̀, ki wọn si fowo ẹ ṣe faaji ara wọn l’Abẹokuta.
Wọn ko ṣẹṣẹ maa ṣe bẹẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa Ogun to gbe wọn jade ṣe wi, o si kere tan, wọn ni wọn ti yinbọn pa eeyan mẹrin ti ko ṣẹ wọn lẹṣẹ kan pato, wọn ti ta ẹya ara wọn ṣe awure.
Orukọ wọn ati ibi ti wọn ti n pitu ọwọ wọn l’Abẹokuta naa ree gẹgẹ bi Kọmandi ọlọpaa Ogun ṣe fi sita: Lekan Ọladipupọ; ẹni ọdun mejidinlogoji (38) to wa lati Abule Ṣotan, Sulaiman Arẹmu; ẹni ọgbon ọdun (30) to wa lati Imala Ẹlẹga, l’Abẹokuta, Ifayẹmi Madru; ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) to wa lati Abule Ṣotan, Shittu Saheed; ẹni ọdun mejidinlọgbọn (38)to wa lati Abule Alarugbo, Samọd Sulaiman; ẹni ọdun marundinlogoji (35) toun naa jẹ ọmọ Ṣotan, Akanji Mọruf, ẹni ọdun mẹtalelogun (23) lati Abule Alabata ati Tajudeen Adekunle; ẹni ọdun mẹrindinlogoji (36) lati Ṣapọn Abẹokuta.
Aṣiri wọn ko deede tu, ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Abraham Okosun, lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Bode-Olude, l’Abẹokuta, pe oun ni koun lọọ ki ẹgbọn oun to n jẹ Sunday Okosun ni, labule Agbara, lagbegbe Mawukọ, l’Abẹokuta, kan naa. Afi boun ṣe debẹ toun ri i pe awọn amookunṣika kan ti pa ẹgbọn oun yii, wọn si ti kun ẹya ara ẹ kelekele, ko pe mọ.
Ifisun naa lawọn ọlọpaa Bode-Olude ṣiṣẹ tọ, wọn lọ sibi ti iṣẹlẹ iku oro naa ti waye, wọn si bẹrẹ iwadii to pada jẹ ki wọn gbọ pe Lekan Ọladipupọ mọ nipa iku to pa ọkunrin naa, wọn si mu un.
Lekan yii lo jẹwọ fun wọn lẹyin iwadii pe oun loun fibọn ibilẹ pa Oloogbe Sunday Okosun. Bo ṣe jẹwọ yii lo ṣatọna bi wọn ṣe ri awọn mẹfa yooku mu.
Ẹnikọọkan wọn naa lo jẹwọ ipa ti wọn ko ninu iku oloogbe yii, wọn si tun sọ nipa eeyan meji mi-in ti wọn ti fiku oro pa.
Eyi to n jẹ Lekan Ọladipupọ naa ṣalaye pe iṣẹ toun ni lati wa ẹni ti awọn yoo pa, o ni ọpọ igba lo jẹ pe ninu igbo loun ti n dọdẹ ẹni toun yoo pa, ni agbegbe Mawukọ yii naa si ni. O loun maa n yinbọn fẹni tori rẹ ba gbabode naa ni, ṣe ẹni naa ko kuku mọ pe apaayan wa ninu igbo to n ṣọ oun, ẹni ẹlẹni to n ṣiṣẹ oko rẹ jẹẹjẹ naa yoo kan ta teru nipaa latọwọ Lekan onibọn ojiji ni.
Boun ba ti paayan tan bẹẹ, yoo pe Sulaiman Arẹmu, iyẹn ni yoo waa kun ara eeyan naa si wẹwẹ pẹlu ada, ti yoo yọ awọn ẹya ara rẹ pataki ti wọn nilo, ti wọn yoo si lọọ ta a fawọn onibaara wọn to ti duro sẹpẹ.
Ta ni awọn onibaara naa? Ifayẹmi Badru, oun lo n ra ọkan, ọwọ atawọn ẹya ara mi-in. Shittu Saheed lo ra ori oku ti wọn pa gbẹyin tọwọ fi tẹ wọn yii, Akanji Mọruf ra ọkan ẹnikan ninu awọn ti wọn ti pa tẹlẹ, nigba ti Tajudeen Adekunle ra ori.
Awọn apaayan yii jẹwọ pe o kere tan, awọn ti pa to eeyan mẹrin pẹlu ilana yii, wọn ni oogun owo ni ẹya ara wọn wa fun, ohun tawọn fi n ṣe niyẹn.
Wọn tun jẹwọ fawọn ọlọpaa pe awọn ni adape orukọ fawọn ẹya ara wọnyi, awọn ki i fi gbogbo ẹnu pe e rara. Fun apẹẹrẹ, wọn ni bọọlu lawọn n pe agbari, transfọma lawọn n pe ọkan, faanu (fan) lawọn si n pe ọwọ.
Irinṣẹ wọn ti i ṣe ibọn ti wọn fi n paayan ati ada ti wọn fi n kun wọn ni awọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.
Nibi to de duro bayii ṣa ni pe CP Lanre Bankọle ti ṣapejuwe iwa awọn eeyan naa bii iwa ọdaju to buru jai. O ti paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ sẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ ipaniyan nipinlẹ Ogun yii, ki wọn wadii wọn si i ki wọn si gbe wọn lọ sile-ẹjọ kia.