Monisọla Saka
Gogoogo ladugbo Ummunnakwo, nijọba ibilẹ Ogbaru, nipinlẹ Anambra, kan laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, pẹlu bi wọn ṣe n ṣọfọ eeyan mẹrindinlọgọrin (76) ti wọn bomi lọ lasiko tọkọ oju omi to n gbe wọn lọ doju de.
Awọn tọrọ ṣoju wọn ṣalaye pe lati ibi afara Onukwu, ni ọkọ oju omi ọhun ti gbera pẹlu ero marundinlaaadọrun-un(85), ọja kan ti wọn n pe ni Nkwo, to wa niluu Ogbakuba ni wọn n lọ.
Alaga igbimọ awọn ikọ to n ṣeto idena agbara nijọba ibilẹ Ogbaru, nipinlẹ Anambra, Pascal Aniegbuna, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin niluu Awka, to jẹ olu ilu ipinlẹ ọhun sọ pe wọn ri awọn bii mẹsan-an kan doola, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe, ọpọ lo padanu ẹmi wọn sinu omi yẹn, ti wọn ko si ti i ri wọn gbe jade.
Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ to wa nibẹ sọ pe loootọ, oun o si nibi ti ọkọ oju omi yẹn ti ko ero, to si ti gbera, ṣugbọn nnkan toun gbọ ni pe, eeyan marundinlaaadọrun-un lo ko, ẹnjinni ọkọ yẹn lo ta ku, tọkọ oju omi naa ṣe yi danu somi.
Bakan naa ni Victor Afam Ogene, fi ijaya ati ẹdun ọkan ẹ han lori iṣẹlẹ ibanujẹ naa. Ogene to jẹ oludije dupo ileegbimọ aṣoju-ṣofin lẹgbẹ Labour Party lọdun to n bọ sọ pe, inu ipayinkeke niluu Ogbaru wa bayii lori iku awọn eeyan wọn. O ni ohun ibanujẹ lo jẹ foun atawọn mọlẹbi awọn oloogbe naa nitori ọfọ nla lo jẹ fun ilu Ogbaru lapapọ.
Ṣaaju akoko yii ni Ogene ti rawọ ẹbẹ sawọn ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nilẹ wa (NEMA), ati ti ipinlẹ wọn (SEMA), lati gba awọn eeyan ilu Ogbaru kalẹ lọwọ omiyale ti arọọda ojo da silẹ lagbegbe naa. O ni awọn ile, oko atawọn ọrọ aje mi-in niluu ọhun lomi ti bajẹ, to si tibẹ sọ awọn ẹlomi-in sinu ipọnju ati ibanujẹ ayeraye.
O waa rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Anambra, lati wa ọna abayọ sọrọ ọṣẹ ti omi n ṣe lagbegbe naa