Eeyan mẹsan-an jona ku ninu ijamba ọkọ loju ọna Ọrẹ si Sagamu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Loju ọna marosẹ Ọrẹ si Sagamu nijọba Odigbo laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, awọn ero mẹsan-an ni wọn jona gburugburu ninu ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe Ọmọtọṣọ, loju ọna Ọrẹ si Sagamu.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Ọgbẹni Sikiru Alongẹ to jẹ alakooso ẹṣọ oju popo ẹka tilu Ọrẹ, o ni ijamba ọkọ naa waye laarin mọto bọọsi Tayota ti nọmba rẹ jẹ FKJ 095 XE, pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ Honda Accord, eyi ti wọn ko ti i mọ nọmba rẹ.

O ni taya ọkan ninu awọn ọkọ mejeeji to fọ lojiji lori ere lo ṣokunfa bo ṣe lọọ fori sọ ọkọ mi-in loju ọna tirẹ to wa.

O ni gbogbo awọn ero mẹsan-an to wa ninu awọn ọkọ naa ni wọn jona gburugburu, ti awọn si ti ko wọn lọ si ileewosan ijọba to wa niluu Ọrẹ.

Ọga awọn ẹṣọ ojupopo ọhun rọ awọn awakọ lati maa ni suuru, ki wọn yago fun sisa ere asapajude, ki wọn si tun maa bọwọ fun gbogbo ofin to rọ mọ iṣẹ awakọ ti wọn n ṣe nitori aabo ẹmi ara wọn.

Leave a Reply